Togo first female prime minister Orílẹ-èdè Togo yan Victorie Tomegah Dogbe gẹgẹ bíi Olóòtú ìjọba obínrin akọkọ

Victorie Tomegah Dogbe

Oríṣun àwòrán, Togofirst.com

Aare Faure Gnassingbe ti kede loni ọjọ Aje pe Victorie Tomegah Dogbe ni yoo jẹ olootu obinrin akọkọ fun orileẹ-ede naa.

Victoire jẹ ẹni ọgọta ọdun, oun ni yoo si rọpo Komi Selom Klassou to kọwe fipo rẹ silẹ lọjọ Ẹti to kọja.

Victorie ti sise gẹgẹ bii adari awọn osisẹ ile ijọba lati ọdun 2009 tẹlẹ

Saa kerin ijọba ni Aare Gnassingbe n lo lọ bayii lẹyin ti wọn tun yan an losu keji ọdun yii.

Bayii, Aare Togo wọle lẹyin ti wọn satunse miran si iwe ofin Togo ki o to le dije du ipo lẹẹkẹrin ni eyi to ti n dari orile-ede naa bayii fun ọpọlọpọ ọdun

Awọn eniyan ilẹ Togo le ni milionu mẹjọ bayii bẹẹ ajakale arun coronavirus naa ja de ibẹ ni eyi to ti jẹ ki eto ọrọ aje Togo tun mọọ lara sii..

Lọdun 2005 lo gba ipo leyin iku baba re Aare Gnassingbe Eyadema to dari orile-ede naa fun ọdun mejidinlogoji ki ọlọjọ to de.