Woman throws her two year old: Ìdí tí mo fi jú ọmọ mi ọmọ ọdún méjì látorí ilé gogoro sílẹ̀

Obinrin kan to ju ọmọ rẹ latoke ile giga kan to kun fun eefin lẹyin ti ina sọ lara rẹ saarin awọn ero to wa nisalẹ nibi rogbodiyan to n waye ni Durban, South Africa ti ba BBC sọrọ.
o ni oun dupẹ gidi lọwọ awọn to tẹwọ gba ọmọ oun la, ọmọ naa yoo ṣẹ pe ọdun meji loṣu to mbọ ni.
"Ohun kanṣoṣo ti mo le ṣe lasiko naa ni lati gba awọn ti mi o mọ gbọ.
Awọn ole lo dana sun ile. Gbogbo wahala naa suyo lasiko ti wọn ju aare Jacob Zuma si atimole.

Wọn ríi labẹ ofin pe o jẹbi lati ma wa jẹ ẹjọ awọn ẹsun ṣiṣe owo ijoba baṣu baṣu lasiko ìṣèjọba rẹ.
Ẹwẹ, oun lo jọwọ ara rẹ fun awọn ọlọpa fún ẹwọn oṣù mẹẹdogun, amọ eyi ti wa bi ifehonuhan nla, idigunjale koda to fi dé ipinle tirẹ gangan náà.
Nkan bi eeyan mejilelaadọrin lo ti ku bayii latari rogbodiyan ọhun.
Bawo ni ọmọ dun meji ọhun ṣe yee?
Ayaworan Ileese BBC, Thuthuka Zondi ká fidio kan tó n ṣafihan arabinrin Manyoni tó n ju Melokuhle sisalẹ lat'ori oke ile gíga ni aarin gbungbun Durban lójó Isegun ti àwọn adigunjale kọlù wọn.
Arabinrin Manyoni gbiyanju lati yolẹ wọ inú àgbàlá ilé keji lati bẹ awọn eeyan ki wọn ran an lọwọ.
Ori aja ikerindinlogun ni wọn wà nigba ti won ri èéfín to n ru soke.
Ero agbeni goke fii kọ lati ṣiṣẹ mọ, arabinrin Manyoni ba sa lati lọ isalẹ ṣugbọn ko seese.
"Ohun gbogbo to ku mi ku mi ku ti mo le ro ni ki n ríi dájú pé ọmọ mi ye".
Ìdí niyi to ṣe ju ọmọ naa silẹ lat'oke sí ọwọ àwọn kan to kàn wá nile.
Asiko ti awọn oṣiṣẹ panapana dé ni nkan bi iṣẹju ogun leyin ti awọn araalu ti n doola awọn eeyan to ha sinu ile naa ni Manyoni to foju kan ọmọ rẹ.
O sọ fun BBC pe oru ọganjọ ni oun to raye wọ inu ile naa.
Idigunjale ti awọn eeyan gunle yii ti mu adinku ba ipese awọn nkan.
Ọpọlọpọ nkan ni ifẹhonuhan to n ṣẹlẹ lọwọlọwọlorilẹede South Africa ti ṣakoba fun leyi to si n fun awn araalu ni ọpọ wahala.














