Aarẹ South African tẹlẹri, Jacob Zuma, yoo f'oju ba'le ẹjọ

Aarẹ orilẹede South African tẹlẹri, Jacob Zuma, ninu aworan kan to ya ninu osu kinni ọdun 2018

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Jacob Zuma yoo f'oju ba ile ẹjọ lori ẹsun iwa ibajẹ, gbigbe owo jade lọna aitọ, jibiti ati iwa ọdaran

Aarẹ orilẹede South Africa ana, Jacob Zuma, yoo f'oju ba ile ẹjọ lori ẹsun iwa ibajẹ mẹrindinlogun (16) to fara pẹ kara-kata ohun ija kan oni biliọnu-biliọnu dollar.

Ẹjọ naa rọ mọ owoo biliọnu meji-abọ dollar kan lori sisọ eto aabo orilẹede naa d'ọtun ni nnkan bi ogun ọdun s'ẹyin.

Awọn ẹsun naa - eleyi ti Ọgbẹni Zuma ni oun ko jẹbi wọn - ni jibiti, gbigba owo lọna aitọ ati gbigbe owo jade lọna aitọ.

Ẹgbẹ oselu African National Congress (ANC) fi tipatipa mu ọgbeni Zuma, to jẹ ẹni ọdun marundinlọgorin (75), lati fiposilẹ losu to kọja.

Ile igbmọ asofin orilẹede naa fẹ dibọ mio-gba-ẹgbọ ẹlẹkẹsan fun ni nigba to fiposilẹ.

Olori agbe fun ijọba, Shaun Abraham, sọ wi pe oun nigbagbọ wi pe ireti wa lati ṣe aṣeyọri ninu ẹjọ naa.

Agbe-f'ọba kan ni onisowo ohun ija tilẹ Faranse, Thales, naa yoo f'oju ba ile ẹjọ.

Zuma

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty

Sugbọn ileese iroyin AFP sọ wipe Thales kọ lati sọrọ lori iroyin yii.

Wọn fi ẹsun kan Ọgbẹni Zuma wi pe o beere owo ẹyin lati ọwọ Thales.

Ẹni to n fun nimọran nipa isuna nigbanaa jẹbi bibeere owo ẹyin lọdun 2005.

Wọn si da Ọgbẹni Zuma duro nipo igbakeji aarẹ nigbanaa.