Ojude Oba festiva 2021: Nítorí ẹ̀dà tuntun COVID-19, Awujale Ijebu Ode, Ọba Adetona wọ́gilé àjọ̀dún Ojude Oba tọdún yìí

Oríṣun àwòrán, other
Awujalẹ ti ilu Ijẹbu, Ọba Sikiru Kayọde Adetọna ti wọgile ajọdun Ojude Ọba ti ọdun yii.
Ninu atẹjade kan ti alamojuto ajọdun naa, Oloye Fassy Yusuf fi sita, bi ajakalẹ ẹda 'Delta variant' arun COVID-19 tun ṣe n gbilẹ sii lo ṣokunfa wiwọgile ajọdun naa.
Atẹjade naa ni kaka ki wọn dẹja tabi gbe awọn eeyan ti yoo peju wa ṣọdun naa nilu Ijẹbu Ode sọwọ ajakalẹ arun naa, yoo dara ki wọn wọgile naa.
- Ẹ wo ibi ọ̀rọ̀ dé dúró lórí àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Tolulope Arotile
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gbé ọ̀kadà iléesẹ́ sá lọ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́
Igba keji niyi ti wọn yoo maa wọgile ajọdun Ojude Ọba lati igba to ti bẹrẹ lọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Ọjọ meji lẹyin ọdun ileya ni wọn maa n ṣe ajọdun Ojude Ọba.
Atẹjade naa ni bi o tilẹ jẹ pe igbesl naa jẹ eyi ti ko dun mọ Kabiyesi Awujalẹ ninu nitori pataki ọdun naa ninu itan ati igbe aye awọn ọmọ Ijẹbu nile loko ati loke okun, sibẹ Ọbalaye naa n gbadura fun alaafia ati aṣejere awọn ibi gbogbo ti wahala ti n suyọ ati gbogbo Naijiria lapapọ.








