Tolulope Arotile: Ǹjẹ́ àwọn ẹbí olóògbé yóò rí ìdájọ́ òdodo gbà?

O ti pe ọdun kan bayii ti atukọ ọkọ ofurufu ileeṣe ọmọ ogun Naijiria, NAF, Tolulope Arotile jade laye.
Lẹyin ọdun kan ti Tolulope di oloogbe, ọpọ ọmọ Naijiria lo ṣi n reti idajọ ododo lori iku rẹ Afurasí lórí ikú Tolulope Arotile ti dé ilé ẹjọ́, èyí ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án
Ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2020 ni Tolulope fi aye silẹ ni ibudo ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ni Kaduna, ti awọn mọlẹbi rẹ si n fẹ ki ijọba ṣe ẹjọ awọn ti wọn gbabọ pe wọn lọwọ ninu iku rẹ.
Baba rẹ, Akintunde Arotile sọ lasiko naa pe o di igba ti oun ba ri idajọ ododo lori iku ọmọ oun ki ọkan oun to le balẹ.
- Ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú sọ orúkọ Tolulope Arotile di mánigbàgbé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà
- Ẹ wo ibi ọ̀rọ̀ dé dúró lórí àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Tolulope Arotile
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gbé ọ̀kadà iléesẹ́ sá lọ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́
- Aya Aarẹ Ghana ati aya ìgbákejì Aarẹ Ghana ti dá gbogbo owó oṣù tí wọ́n gbà láti 2017 padà sápò ìjọba
- Ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n bá lórí kerewà bọ́ sọ́wọ́ Ọlọ́pàá ẹ̀sìn Islam
Tolulope jẹ ọkan gboogi lara awọn ọmọ ogun ofurufu Naijiria ti wọn n fi imu awọn ẹgbẹ agbesumọmi Boko Haram danrin, eyii to mu ki ọpọ eeyan gbagbọ pe ejo lọ n nu lori iku rẹ.
Ninu atẹjade ti olukoro ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu, Ibikunle Daramola fi lede, o ni ọkọ to n fẹyin rifaasi lo ṣeṣi pa Tolulope.
Ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria, to fi mọ Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, ati minisita fun irinna ọkọ ofurufu tẹlẹ, Femi Fani-Kayode, lo sọ pe itan alọ ijapa ati yanribo lasan ni ileeṣẹ naa n sọ.
Ṣaaju ni ile ẹjọ majistreti kan ni Kaduna ti kọkọ tu awọn afurasi meji kan silẹ, iyẹn Folorunsho Igbekele ati Gbayegun Deji loṣu Kẹjọ ọdun to kọja lẹyin to ni ero ọkọ to pa oloogbe naa lasan ni wọn jẹ, ko si si ẹri pe wọn lọwọ ninu iku rẹ.
Ẹwẹ, ireti wa pe wọn yoo pada gbe Nehemiah Adejor lọ sile ẹjọ lori ẹsun pe o lọwọ ninu iku Tolulope ni ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan an, ọdun kan naa, ṣugbọn ọpọ ni ko mọ ibi ti ọrọ naa de duro titi di asiko yii.
- Ó kéré tán, ajínigbé ti pa èèyàn 222 láàrìn oṣù mẹ́ta ní Kaduna- Gomina El Rufai
- Sunday Igboho, Akintoye àtàwọn míràn fa Buhari, Malami àtàwọn míì lọ síwájú ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Emmanuel kó sí gbaga ólọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó lu ìyàwó rẹ̀ pa nítórí ó kọ ìbálòpọ̀
- Wọ́n ní Ìyá Esabod yẹn ma ń ṣépè, fi òṣèré wọ́lẹ̀, mò ń retí èsì yín sí ọ̀rọ̀ tí mo fi síta yìí - Mr Portable
- Ìjọba Gombe kọ́ iléẹ̀kọ́ tuntun sí ẹgbẹ́ àwọn iléeṣẹ́ elétò aàbò kí ọwọ́ ajínigbé má tẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ mọ́
- Wọ́n ní Ìyá Esabod yẹn ma ń ṣépè, fi òṣèré wọ́lẹ̀, mò ń retí èsì yín sí ọ̀rọ̀ tí mo fi síta yìí - Mr Portable
- Mọ si nípa àbá òfin tí yóò mú kí ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti le gbẹ́sẹ̀ lé ilé tàbí ilé ìtura tí ífipá bálòpọ̀ bá ti wáyé
Laarin ọdun meji pere ti Tolulope darapọ mọ ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu, o gba oriyin lọdọ Aarẹ Muhammadu Buhari fun iṣẹ takun-takun to ṣe.
Ni bayii, ọpọ ọmọ Naijiria lo ṣi n reti irufẹ idajọ ti yoo kan awọn ti wọn fura si lori iku oloogbe ọhun, paapaa nitori bo ṣe sin orilẹ-ede Naijiria tọkan-tọkan.
- Kò sọ́jà mọ́! A ti ti Ọjà Ladipo pa nítorí rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀ - `ijọba ìpínlẹ̀ Eko
- Ẹ̀ṣọ́ ìyàwó Gómìnà Ekiti Bisi Fayemi bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ l'Abuja
- Àfinra! Ẹ wá máa lọ ilé ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ títí di ọjọ́ wájú, a ti ti ìbugbé ilé ẹkọ́ pa torí Covid-19 - Fásitì Unilag
- Oríire ńlá ló jẹ́ fún àwọn ọmọ Naijiria pé orílẹ̀-èdè yìí ṣì wà ní ọ̀kan ṣoṣo- Buhari
















