Yoruba movie: Kìí ṣe Iya Esabod tó fẹ máa fi wa pawo lóríi YouTube rẹ ló má máa da ẹgbẹ TAMPAN rú

Aworan Portable ati Esabod

Oríṣun àwòrán, Google

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja osere onitiata, Olu Olowogemo ti ọpọ mọ sí Mr. Portable ti da fi oko ọrọ ranṣẹ sí gbajugbaja sọrọ sọrọ ori ayelujara, Esther Aboderin to tun n jẹ Esabod lori bo ṣe ni oun(Esabod) gan lo n da aarin awọn oṣere ru.

Portable ni ninu Fidio ti oun kọkọ ṣe jáde, òun o fẹ ki wọn si oun gbọ rárá tori kii ṣe pe oun ni bi ààrẹ ẹgbẹ TAMPAN ìyẹn Mr Latin tori onirẹlẹ ati olufẹ alafia ni latile.

Amọ ọ ni "iya to n yeye awọn agbalagba iṣẹ tiwa, Esabod ni mo n bá wi".

Portable ni oun mọ Latin dáadáa gẹgẹ bí ẹni tó nífẹẹ alafia, o ni apa ibẹ yẹn gangan ni ọta fẹ fi wọlé síi lara. Tori naa ki awọn èèyàn ma ri ààrẹ àwọn gẹgẹ bí ẹni tí kò dára tàbí tí kò mọ ọrọ sọ.

"Ojú tí mo fẹ kee fi woo ni wí pé ọnà ibi tí wọn fẹ fi ko ààrẹ mi ni papamora lati le da ọgbọn ba nkan jẹ mọ ọ lọwọ".

Portable ni awọn mọ pe o to oye yẹn jẹ láti ọjọ tí àwọn ti fi je é.

Ṣe ni Portable dari ọrọ rẹ taara lọ sọdọ arabinrin Esther Aboderin (Esabod) pe ko dẹkun láti máa yẹyẹ awọn agbalagba ẹgbẹ TAMPAN.

"Ti ẹgbẹ wa tabi iṣẹ wa ba ni problem, kii ṣe Iya Esabod tó n wa nkan to máa mu oju òpó YouTube rẹ gboro lati ri ounjẹ jẹ ló má wa máa parí ìjà ẹgbẹ wa".

O ni ti àwọn ba ríi pé ipá àwọn o kaa mọ, awon agbalagba inu ẹgbẹ mọ awọn to ye ki wọn pe lati wa pari aawọ aarin awọn. O ni kii se eeyan tó jẹ pe pipa ni lerin bíi tàwọn loun naa fi ni jẹun ni yóò máa wá pari ija.

Portable ni oun gbọ pé ìyá Esabod maa n ṣepe, o si máa n fún Gbogbo èèyàn lesi tori náà oun n reti èsì lọdọ rẹ.

O koro oju sí bo ṣe ni o ni dótì awọn àgba ẹgbẹ to jẹ pe awọn eeyan bọwọ fún tẹlẹ.

Mr Portable

Oríṣun àwòrán, Mr Portable/Mr Latin

Mr. Portable sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Mr. Latin lórí gbas-gbos tó ń wáyé lágbo òṣèré tíátà Yoruba

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Olu Olowogemo Arijan, ti ọpọ eeyan mo si Mr. Portable ti bu ẹnu atẹ lu awọn olori ẹgbẹ awọn oṣere tiata, TAMPAN, lori awuyewuye to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ naa.

O fi kun un pe awọn kan ti sọ iṣẹ́ tíátà di ibi tí wọ́n tí ń polówó iṣẹ́ aṣẹ́wó.

O ni oju gba oun ti fun ẹgbẹ ọhun, paapaa awọn adari wọn bi wọn ko ṣe le yanju awọn rogbodiyan to n ba ẹgbẹ naa finra lasiko yii.

Mr. Portable lo sọ ọrọ naa ninu fidio kan fi ledeloju opo Instagram rẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn oṣere jẹ ẹgbẹ kan ti awọn araalu maa n bu iyi fun lawọn asiko kan sẹyin, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ mọ bayii.

O ni "Awọn eeyan maa n pọn wa le tẹlẹ nitori a maa n mu inu awọn araalu dun, ṣugbọn ẹgbẹ naa ti wa di ẹgbẹ ti awọn kan n ṣoro si abuku si bayii."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

"Onikaluku ti n ṣe ohun to wu wọn bayii lai si ọwọ fun awọn agbalagba, ẹyin ti ẹ wa jẹ ọga wa naa ẹ wa jokoo, ẹ wa n wo wa niran."

Gbajumọ osẹre naa bu ẹnu atẹ lu Aarẹ TAMPAN, iyẹn Mr Latin, lori bo ṣe gba lati ṣe ifọrọwerọ pẹlu obinrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Esabod lori opo Instagram.

Àkọlé fídíò, Ibeju Lekki Free Trade Zone: A ti bí ọmọ tó lọ Fásitì tí kò rí iná ọba rí- Olawale Eleto

Obinrin Esabod naa jẹ gbajumọ laye ara rẹ, ṣugbọn ọpọ eeyan ni ko gba tirẹ nitori irufẹ awọn ọrọ kabiti-kabiti to maa n n sọ lori afẹfẹ.

Mr Portable ni "Aarẹ ẹgbẹ wa lọ ṣe ifọrọwerọ pẹlu Esabod lati wọ orukọ ẹgbẹ wa nilẹ nibi to ti n tọrọ aforiji ni orukọ Jide Kosoko."

Mr Latin

Oríṣun àwòrán, mrportableharejan

Ninu erongba Mr Portable, ẹgbẹ awọn oṣere lagbara lati da seria fun ọmọ ẹgbẹ to ba tasẹ agẹrẹ lai lọ tọrọ aforiji ni gbangba, paapaa niwaju ẹni ti ki ṣe ọmọ ẹgbẹ naa.

O ni "Aarẹ wa n kawọ pọ lati rojọ niwaju Esabod to jẹ pe isọkusọ lo maa n sọ lori ayelujara."

"Ta ni Esabod yii gan... bawo ni ti ẹ ṣe jẹ!"

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

Oṣere ọhun ni iṣe gidi ni iṣẹ tiata tẹlẹ, ṣugbọn wọn ti sọ iṣẹ naa di eyii ti wọn fi n polowo iṣẹ aṣẹwo bayii.

Mr. Portable pari ọrọ rẹ pe ko bojumu ki awọn kan maa n yẹyẹ awọn agba oṣere.

Lẹyin naa lo ke si awọn adari ẹgbẹ TAMPAN lati ṣe atunṣe.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams