Lizzy anjorin Vs Toyin Abraham: Àwọn òṣèré tó ń fi àdúrà ré èpè ESABOD kúrò lóríi Toyin rèé

Toyin Abraham

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn oṣere akẹgbẹ Toyin Abraham ti n rọjo adura le e lori latari ija to tun pa oun ati akẹgbẹ rẹ Lizzy Anjorin pọ.

Eyi da lori ija to bẹrẹ laarin Toyin ati Lizzy ni nkan bii ọdunmeji sẹyin nigba ti Toyin bim ti Lizzy ni isọ awọn alagbo elewe ọmọ lo bimọ si to si jẹ pe fidio họsibitu awọn oyinbo ni Toyin fi sita.

Ọpọ eeyan lo ti kọkọ ro pe aawọ to wa laarin awọn osere tiata mejeji, Lizzy Anjorin ati Toyin Abraham ti jẹ rodo, lọ ree mumi ni.

Amọ kaka kewe agbọn ọrọ yii dẹ ṣe lo tun pele sii lọjọ diẹ sẹyin.

Ṣe ni igbesẹ gbajugbaja agbohunsafẹfẹ lori ayelujara Esther Aboderin ti ọpọ mọ si ESABOD tun bu bẹntiroo si i ti fidio kan jade nibi to ti n fi kobiewu wọn epe le Toyin ati ọmọ ati ọkọ rẹ lori.

Àkọlé fídíò, King Sunny Ade's son: Ohùn orin bàbá mi nìkan kọ ni l’Ọlọrun fún mi, ijó bíi kòkòrò ni ṣáá
Àkọlé fídíò, 'Èmi ọmọ Ikorodu ọ̀ga, ọmọ aṣalẹ̀ jẹ́jẹ! Wo bí àwọn ọmọdé tó "tuush" yìí ṣe ń fi oríkì Yorùbá dábíra

Nigba to ya, to gbọ latẹnu awọn mejeeji ti ọrọ kan, ni mama ni gẹgẹ bi agbalagba oun fẹ pari ija to wa laarin wọn.

Ẹwẹ ninu gbogbo eleyii, gbajugbaja oṣerekunrin Femi Adebayo ati agba ogbontarigi oṣerebinrin Joke Silva bọ soju opo Instagram wọn lati gboriyin fun Toyin Abraham ti wọn si n gbadura fun un.

Gẹgẹ bí Joke ṣe sọ ninu ọrọ ti o fi sita, "Oluwatoyin ọmọ Abraham, aya Ajeyemi, Iya Ire, oṣere to dantọ, ki Ọlọrun ko bukun fun ẹ".

Joke Silva tun gbadura fun Toyin wipe epe kepe ko ni duro lori rẹ to si ni ẹjẹ Ọba to n sin bo o.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Toyin Abraham mọ riri adura yii gidi gan to si fi esi idupẹ si oju opo rẹ pe o ti gbe ẹmi oun ro pada pẹlu adura yii.

Ni ti Femi Aebayo ti oun naa jẹ ọmọ agba oṣere, oun tilẹ ke pe gbogbo eeyan ki wn ba oun rjo adura le Toyin lori ni.

"Oluwatoyin ọmọ Abraham, aya Ajeyemi, Iya Ire, oṣere to dantọ, ki Ọlọrun ko bukun fun ẹ, ẹyin eeyan ẹ jọwọ ba mi rọ aduro bo Toyin o!

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

O fẹ da bii pe ati Femi Adebayo ati Joke Silva jọ wa lori itage ere sinima tuntun kan ti Toyin fẹ gbe jade ni.

Ṣe ni Toyin tun mọ riri atẹjade ti Femi Adebayo ṣe yii to si fesi pe "Bọda Femi, mo fẹran yin gan, mi o si le duro ki gbogbo aye ri i...

Àkọlé fídíò, Democracy day 2021: Kí ni Nàìjíríà ti jèrè lára gbogbo ààrẹ tó ti jẹ látọdún 1999?