Major General Farouk Yahaya: Ààrẹ Buhari tí yan olórí ikọ̀ ọmọogun Naijiria tuntun

Major General Farouk Yahaya

Oríṣun àwòrán, Defence HQ

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti yan Ọgagaun Major General Forouk Yahaya gẹgẹ bi Adari ikọ awọn ọmọogun ori ilẹ ni Naijiria.

Ninu atẹjade ti ẹka iroyin ileeṣẹ ọmọogun Naijiria fi lede ni iroyin naa ti han si awọn araalu.

Ọgagun Farouk ni oun dari ikọ awọn ọmọogun Naijiria to n koju ikọ Boko Haram ni ariwa orilẹede Naijiria, ti wọn pe ni HADIN KAI.

Aarẹ Buhari yan adari ikọ tuntun fun awọn ọmọogun Naijiria naa lẹyin ijamba ọkọ ofurufu to mu ẹmi Ọgagun Ibrahim Attahiru lọ ati awọn ọmọogun mẹwaa miran.

Ileeṣẹ ikọ ọmọogun ofurufu naa ni awọn ṣi n ṣe iwadii ijamba ọkọ ofurufu to waye ni tosi papakọ ofurufu to wa ni ilu Kaduna.

Tani Ọgagun Farouk Yahaya ti wọn ṣẹṣẹ yan?

  • Ọgagun Faruk Yahaya lo n dari ikọ ọmọogun to n gbogun ti Boko Haram lọwọlọwọ ni iwọ ariwa orilẹede Naijiria.
  • Ipinlẹ Zamfara ni Faruk Yahaya tisẹ wa, to si di ipo gboogi mu ni ikọ ọmọogun Naijiria.
  • Saaju o ti fi igba kan di ipo adari ikọ ọmọogun ilẹ Naijiria ri, iyẹn Commander of the Armed Forces.Ọgagun Faruk Yahaya