Children's Day 2024: Wo àwọn ọmọdé tó gbọ́ èdè abínibí rẹ jù ẹ lọ
Ara ọtọ ni BBC Yoruba gbe ayẹyẹ ayajọ ọjọ awọn ewe ti ọdun yii gba.
Awọn alejo nla nla to ko eyin wa sita la gba fun ọjọ toni gẹgẹ bi awọn ọmọ naa ṣe n fi ede Yoruba dara lọna ti wọn mọ ọ de.
Laarin ọdun mẹrin si mẹfa pere ni ọjọ ori awọn ọmọde yii, nitori naa wọn ko tilẹ tii de ileewe girama rara. Ọmọ ti ko tii to ọdun mẹta naa wa lara wọn pẹlu.
Bawo ni awọn ọmọ yin ṣe mọ nipa yin to?
Ki ni o ti kọ wọn nipa ara wọn?

Ṣe wọn tilẹ mọ orukọ baba ati iya wọn tabi o ni orukọ ti wọn mọ yin si?
Ṣe o kọ wọn nipa orilẹede ti wọn ti wa?
Orin ede Yoruba wo ni wọn mọ abi ti akata ni ni gbogbo igba?
Bi iwọ o ba le ki oriki ara rk kori rẹ wu, ṣe o ṣaa jẹ ko wu awọn ọmọ lati fẹ́ran oriki ara wọn ati ti ilu wọn?
...BBC Yoruba n ṣe eyi lati kọ awọn ewe ni pataki mimọ nipa orirun wọn ati pataki aṣa ati iṣe ilẹ kaarọ o jiire.