Children games Akomolede àti Asa: Wa wo èré èyí tó yẹ fún àárọ̀ kùtù àti èyi tó wà fún òṣùpá

Àkọlé fídíò, Wa wo èré èyí tó yẹ fún àárọ̀ kùtù àti èyi tó wà fún òṣúpá

"Ẹkun mẹẹran, mẹẹ, o mu dudu, mẹ́ẹ, o mu pupa, mẹẹ..."

Pẹlu apẹrẹ lawọn akẹkọọ naa fi darapọ mọ eto ti tonii lati ṣe ere idaraya "bojuboju o".

Ọmọwe lo n kọ wa lori eto Akomolede ati Aṣa Yoruba tonii. Ọmọwe Yetunde Olaleye-Awolusi lati ileewe Chirist Way High School niluu Ile Ife lo mu wa lọ si iranti bi ere idaraya ṣe maa n ri laye atijọ.

Yoruba gbagbọ pe lẹyin iṣẹ oojọ, o yẹ ki isinmi ati igbadun wa.

Lasiko ti awọn agbalagba ba n ta ayo ni àwọn ere oṣupa mii maaa n jẹ jade latọdọ awọn ọmọde nita gbangba ki wọn to wọle sun.

Koda ẹ kan le ma mọ ni, oriṣiriṣi isọri ni a pin ere idaraya nilẹ Yoruba si labẹ aburada meji gboogi ti olukọ pe ni "Ojumọmọ" ati "Ere Oṣupa".