Apam beach: Ọlọ́pàá ní àwọn ríbi dóòlà ọmọdé méjì ṣugbọn méjìlá bá odò lọ̀ ní Ghana

Oríṣun àwòrán, Adom News
Alukoro ọlọpaa DSP Irene Oppong ni Cape Coast sọ pe awọn gbẹsun kan lati ọdọ Kwame Akono ni nkan bi ago mẹjọ alẹ kọja.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa iku awọn ọmọde mejila to lọ wẹ lodo Apam Beach lagbegbe aarin gbungbun ilẹ naa lorileede Ghana.
Iṣẹlẹ yi waye lọjọ Kẹjọ oṣu Kẹta ọdun yii.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe naa fi sita, wọn ni ''wọn gbe oku awọn ọmọde mejila ọhun jade lodo ti wọn si doola ẹmi awọn meji''
Ninu ọrọ rẹ, Akono sọ pe ibatan rẹ Joshua Annor ẹni ọdun mẹẹdogun ti bodo lọ lasiko to lọ gba bọọlu lẹgbẹ odo pẹlu awọn ọrẹ rẹ.
Niṣe latẹjade naa sọ pe awọn ọlọpaa sare lọ sibẹ lati lọ mọ ohun to ṣẹlẹ.
''Ori ba wa ṣe e, a ribi doola Simon Dadzie ọmọọdun mẹẹdogun ati Godfred Appretsie ọmọọdun mẹrinla ti wọn si n gba itọju nile iwosan''
O tẹsiwaju pe awọn pada ribi yọ oku mejila mii lodo ti ọjọ ori awọn ọmọ naa si jẹ bi ọdun mẹrinla si mẹtadinlogun lwourọ ọjọ Aje. Obinrin meji wa ninu wọn.
Bẹẹ ni awọn ọlọpaa sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lati mọ ohun to ṣẹlẹ ni pato.
Igbiyanju ṣi n tẹsiwaju lati ṣawari awọn miran to ba ṣi wa ninu omi naa.
Iroyin to n tẹwa lọwọ ti a ko ridi rẹ fi mul sọ pe o top awọn ọmọde ogun to gba ọna ẹburu lọ wẹ lodo naa.
Awọn araadugbo sọ pe nitori ilana Covid-19 to wa nita awọn ọmọ yi y jade lati lọ wẹ lodo ni nitori ko si igbalaye lati wẹ nibẹ.
Wọn nitori ọna ti wọn gba yi ni wọn ko fi tete mọ pe wọn ko si odo titi di ọjọ Aje lati ọjọ Aiku ti wọn ti lọ.
Ko daju bi awọn agbofinro ko ṣe mọ pe awọn ọmọ yi yọ gb'ọna ẹburu lati lọ we lodo.















