Orisabunmi, Ibidapọ-Obe, Akin Olugbade, Martins Kuye, Lateef Jakande: Àwọn eèkàn ọmọ Yorùbá tó ti jáde láyé lọ́dún 2021 nìkan

Awon oju to ti lọ

Oríṣun àwòrán, others

Wo àwọn eèkàn ọmọ Yorùbá tó ti jáde láyé lọ́dún 2021 nìkan

Ọdun to ti mu ọpọlọpọ la oriṣiriṣi nnkan kọja ni ọdun 2021 jẹ bi o tilẹ jẹ pe ko tii ju ọsu mẹta lọ ti ọdun naa bẹrẹ.

Ọpọlọpọ to ku ni iku wọn ko ṣẹyin ajakalẹ arun COVID-19 ti awọn miran si tun ku iku miran yala nitori ọjọ ogbo, ikọlu awọn agbebọn darandaran, ijamba ọkọ tabi awọn aisan miran.

Eyi ni akọsilẹ awọn orukọ awọn eekan ọmọ Yoruba to ti di araalẹ laarin oṣu mẹta akọkọ lọdun 2021.

Ibidapo-Obe

Oríṣun àwòrán, @Ibidapo-Obe

1.Ọjọgbọn Ibidapọ-Obe:

Purofẹsọ Ibidapọ-Obe ni giwa faisiti ilu Eko, UNILAG tẹlẹ.

Bakan naa lo tun fi igbakan ri jẹ giwa fun fasiti Alex Ekwueme Federal University ni ilu Ndufu-Alike.

Àkọlé fídíò, Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èy

Ọjọgbọn Oyewusi Ibidapo-Obe jade laye ni ọjọ kẹta, oṣu kini, ọdun 2021.

Ohun ti araye gbọ ni pe aarun COVID-19 lo ṣokunfa iku rẹ.

Iyalẹnu nla ni iku rẹ jẹ fun ọpọlọpọ awọn eeyan paapaajulọ lagbo ẹkọ lorilẹede Naijiria ati lagbaye.

Orisabunmi

Oríṣun àwòrán, @Orisabunmi

2. Arabinrin Folake Aremu (Orisabunmi):

Eekan elere itage ati sinima ni arabinrin Folake Aremu ti ọpọlọpọ mọ si Orisabunmi.

Ọjọ karun un, oṣu kini ọdun 2021 ni Oriṣabunmi jade laye.

Àkọlé fídíò, Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala

Iku rẹ si fẹ afẹfẹ ibanujẹ nlanla si agbo awọn oṣere tiata.

Ọmọ ilu Olla ni ipinlẹ Kwara ni Oriṣabunmi, ẹni õgọta ọdun si ni nigba to jade laye.

Lẹyin oṣu mẹrin ti ọkọ rẹ tẹlẹ, Jimoh Aliu jade laye ni iku mu oun pẹlu lọ.

Folabi Olumide

Oríṣun àwòrán, @Folabi Olumide

3. Ọjọgbọn Folabi Olumide:

Ọjọgbọn Folabi Olumide ni giwa akọkọ fun fasiti ipinlẹ Eko, LASU, ọjọ Ẹti ọjọ kẹjọ oṣu kini ni wọn ju awà silẹ.

Aisan ranpẹ lo muu lọ si alakeji lẹni ọdun mọkanlelọgọrin.

4. Aare Boluwatife Akin-Olugbade:

Aare Boluwatife Akin-Olugbade ni Aare Ona Kakanfo ti Owu nilu Abẹokuta.

Lagbaye ni wọn ti mọ si ọkan gboogi lara awọn to nifẹ ọkọ Rolls-Royce julọ.

Aare Boluwatife Akin-Olugbade

Oríṣun àwòrán, @Akin-Olugbade

Ọjọ kẹrinla, oṣu kini, ọdun 2021 ni ajakalẹ arun COVID-19 wọle mu u lọ.

Amofin to kọṣẹmọsẹ gboye ọmọwe ninu imọ ofin nipa ileeṣẹ ni ni fasiti Cambridge.

Ọkọ Rolls Royce mẹwaa ni oun nikan niti owo rẹ n lọ si ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira.

Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta ni ki ọlọjọ to de.

5. Martins Kuye:

Martins Kuyẹ fi igbakanri jẹ minisita fun ọrọ iṣuna lorilẹede Naijiria.

Eekan ẹgbẹ oṣelu PDP si ni pẹlu ki o to jadelaye ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kini ọdun 2021.

Onimọ nipa ibagnepọ ẹda( socioloist) ati ọrọ aje (economist) ni.

Igba meji ọtọtọ lo si gbiyanju ati di gomina ipinlẹ Ogun ṣugbọn ti ko bọ si ki ọlọjọ to de.

Martins Kuye

Oríṣun àwòrán, @Martins Kuye

6. Alhaji Lateef Jakande:

Gomina tẹlẹ fun ipinlẹ Eko, Lateef Jakande jade laye ni ọjọ kọkanla oṣu keji ọdun 2021.

Ẹni ọdun mọkanlelaadọrun ni Baba kekere nigba to jade laye.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award'ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀

Akọroyin to dantọ ni ki o to di gomina ipinlẹ Eko laarin ọdun 1979 si 1983.

Nigba to ya, o di minisita fun iṣẹ ode labẹ iṣejọba Ọgagun Sani Abacha laarin ọdun 1993 si 1998.

Àkọlé fídíò, Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala