Akute NNPC Fire Incidence 2021: Iná ń jó lọ́wọ́ ní Akute nitòsí Berger báyìí

Akute

Awọn panapana ipinlẹ Eko ti de sibẹ ni kopẹ ti awọn ara Akute ranṣẹ pe wọn.

Akute

Wọn si ti pa ina naa to ṣẹyọ ni Akute ni idaji oni.

Akute

Àwọn panápaná ti pa iná tó ṣẹ́yọ nídàjí òní nílé epo NNPC ní Akute nitòsí Berger báyìí

Akute

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe ina n jo bayii ni Akute ni ipinlẹ Ogun nitosi Berger.

ak
Àkọlé fídíò, Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èy

Iná ń jó lọ́wọ́ ní Akute nitòsí Berger báyìí

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe ina n jo bayii ni Akute ni ipinlẹ Ogun nitosi Berger.

Akute

Arakunrin Tolu ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe ina naa deede sọ nile epo NNPC to wa lẹgbẹ Ajayi Farm Bus stop ni Akute.

O ni ọkọ agbepo kan kan fẹ ja epo sinu agba nile epo naa ni ina deede ṣẹyọ.

Akute

O ni wọn gbiyanju lati fi apa ina Fire Extinguisher pa ina na sugbọn ẹpa ko boro mọ.

Ina naa ti ran opo ina ati waya rẹ ti epo rọbi sti ti da sinu gọta ni eyi ti ina naa n gba ran kakiri.

Bayii ọpọ awọn eeyan ti n gbiyanju lati pa ina naa lara awọn ile kọọkan ni Akute.

Wọn ti n pe awọn panapana bayii ni agbegbe Akute.

Akute

BBC yoo maa mu gbogbo bo ba ṣe n lọ wa fun un yin loju opo yii