Afurasí daran-daran méjì tó pa àgbẹ̀ di èrò ẹ̀wọ̀n ní ìpínlẹ̀ Ondo

Daran-daran to gbe ibọn dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Daran-daran meji, Babuga Mallam ati Manu Abubakar ti di ero ọgba ẹwọn fun pe wọn pa agbẹ kan, Adebayo Festus Adebayo, ẹni ọdun mọkanlelaadọta.

Ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati mejidinlogun ni awọn mejeeji.

Iwe iroyin The Nation jabọ iroyin pe awọn afurasi mejeeji pa ọkunrin naa ni nkan bi aago meji ọsan, ni ọjọ karun-un, oṣu Keji, ni oko rẹ to wa ni ilu Ajowa-Akoko.

Ọlọpaa to ko wọn lọ sile ẹjọ, Mary Adebayo sọ pe ẹsun naa tako ofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Ondo fun ọdun 2016.

O rọ̀ ile ẹjọ naa lati fi awọn afurasi si ọgba ẹwọn titi di igba ti abajade imọran Oludari ẹka igbẹjọ yoo fi jade.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award'ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀

Eyi si lo mu ki onidajọ N. Aduroja fi awọn afurasi mejeeji si ọgba ẹwọn Olokuta.

Wọn ti sun igbẹjọ wọn si ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun 2021.

Àkọlé fídíò, Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala