Afurasí méje tí wọ́n ló jó ilé Asabi Olórìṣà n'Ilorin fojú balé ẹjọ́

Aworan awon lọya ni kootu naa ati Asabi Oloriṣa
Àkọlé àwòrán, Aworan awon lọya ni kootu naa ati Asabi Oloriṣa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn eeyan meje ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu sisọ ina si ile iya onisẹse kan ti a mọ si Toyin Asabi Oloriṣa, ti foju ba ile ẹjọ.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii ni wọn fi oju Alhaji Yekini Oloruntele, Alhaji Saliu Usman, Garba Amuda Yusuf, Alhaji Mumini Showa, Imam Isiaq Raji, Alhaji Saliu Abubakar ati AbdulMumini Muhamed ba ile ẹjọ giga ilu Ilorin.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kin-in-ni, osu Kin-in-ni ọdun 2026 yii ni iroyin gbe e, pe ina jo ile iya onisẹse naa, Toyin Asabi Olorisa.

Lẹyin ọjọ diẹ sigba naa ni a tun gbọ pe awọn ọlọpaa ti mu awọn eeyan meje ti wọn furasi lori iṣẹlẹ naa.

Asabi Olorisa lo pe wọn lẹjọ nipasẹ agbẹjọro rẹ, Abdulmumeen Busari, ti ẹka to n ri si eto ofin nipinlẹ Kwara.

Báwo ni ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ nílé ẹjọ́?

Awon eeyan ni kootu naa

Ni ibẹrẹ igbẹjọ, ile ẹjọ ka ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi meje naa si wọn leti ni ọkọọkan.

Ẹsun naa lọ bayii:

"Pe ni ọjọ kin-in- ni osu kin-in- ni ọdun 2026, Alhaji Yekini Oloruntele, Alhaji Saliu Usman, Garba Amuda Yusuf, Alhaji Mumini Showa, Imam Isiaq Raji, Alhaji Saliu Abubakar AbdulMumini Muhamed ati awọn mii-in ti wọn sa lọ gbimọ pọ lati se isẹ laabi.

"Ẹ mọọmọ sọ ina sile to jẹ ile gbigbe fun Arabinrin Toyin Asabi Olorisa, ina naa si jo ile rẹ.

"Fun idi eyi, ẹ da ẹsẹ ti o ni ijiya labẹ ofin ilẹ wa."

Lẹyin eyi ni gbogbo awọn afurasi naa dahun pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Agbẹjọro Iya Ọsun rọ ile ẹjọ lati fi wọn si ọgba atunse ti ijọba, sugbọn agbẹjọro I.F Yusuf to gbẹnu awọn yooku rẹ sọrọ tako ipe naa.

Ìdájọ́

Lẹyin atotonu awọn mejeji, Adajọ agba Mahmud Gafar sọ pe, niwọn igba ti awọn ọlọpaa ti kọkọ fun wọn ni beeli, ile ẹjọ naa yoo fun wọn.

O fun aaye beeli silẹ fun ẹni kọọkan wọn pẹlu miliọnu meji naira (N2.5million) ati oniduro kọọkan.

O wa sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹrindinlọgbọn, osu Kẹta ọdun yii.

Àwọn onísẹ̀se ti ra ilé fún mi - Asabi Olorisa

Ninu ifọrọwerọ pẹlu Asabi Olorisa lẹyin igbẹjọ, o dupẹ lọwọ awọn Onisẹse fun atilẹyin wọn.

Asabi Oloriṣa sọ pe: "Awọn Onisẹse ti dìde, wọn ti ra ile fun mi ki n ma baa sun ita".

Tẹ o ba gbagbe, lasiko ti Iya Oloriṣa yii ti ilẹ ọdun to lọ de lo ri i pe ile oun ti jona patapata.

Ninu fidio to ṣafihan rẹ ninu ile to jona ọhun ni Asabi Oloriṣa ti n pariwo pe kawọn Oniṣẹṣe dide si ọrọ yii o.

Iya naa n pariwo pe oju ti awọn Oniṣẹṣe bi wọn ba fi le jẹ ki ìya yii jẹ oun gbe.

Bẹẹ lo ni oun ki i ṣe ọdun iboriṣa oun niluu Ilorin ti oun kọle naa si, bi ko ṣe pe ilu abinibi oun loun maa n lọ lati ṣọdun.

Mama naa ṣalaye ninu fidio ọhun, pe ọdun ni oun lọọ ṣe niluu oun gẹgẹ bii ti tẹlẹ, to fi di pe wọn pe oun lojiji pe wọn ti sọ ina sile , gbogbo ẹ si ti jona tan pata.