Prophet Muyideen Kasali: Ìjà ti parí láàrín wòlíì Kasali àti Bunmi Olasehinde tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́

Oríṣun àwòrán, @DailyPostNGR
Gbajugbaja ajihinrere ati Wolii, Muyideen Kasali ati iyawo rẹ aarọ, Bunmi Olasehinde ti pari ija to wa laarin wọn.
Gẹgẹ bii ohun ti Wolii naa sọ, ọdun mẹta gbako ni tọkọtaya ọhun fi tuka ki ija to pari.
Tọkọtaya naa fi ẹri ifẹ wọn han ni gbagede isọji ita gbangba kan, nibi ti Wolii Kasali ti pe obinrin naa jade si ori aga iwaasu, to si fi ọwọ kọ ni ọrun.
- Ilé ẹjọ́ sọ àwọn afurasí méje sí àtìmọ́lé lóríi rògbòdìyàn tó wáyé ní ọjà Ṣaṣa
- Àwọn Agbébọn ti dáná sún agbègbè Maru nípinlẹ̀ Zamfara, wọ́n tún jí èèyàn tó lé lọ́gọ́ta gbé lọ
- Àwọn ará abúlé kan ṣàwàrì àlùmọ́ọ́nì gòólù ní wọ́n bá kígbe síta ní Ọlọ̀pàá bá yi wọn ká!
- Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sadiq Daba 'Inspector Waziri' nínú sinimá October 1 tó jáde láyé rèé
- Baba tó dàbí MC Oluomo láyé yìí kò sí, ẹni tó bá níi, ó ní ohun gbogbo- Ọmọ MC Oluọmọ
Lẹyin naa ni Kasali sọ fun obinrin naa pe "ṣe o mọ pe mo ni ifẹ rẹ gidi" ti obinrin ọhun si fesi pe oun naa nifẹ Wolii Kasali.
Kasali wa sọ fun obinrin naa pe "oo ni ṣe bẹẹ mọ abi?" iyawo rẹ ọhun si fesi pe "mi o ni ṣe bẹẹ mọ, ẹyin naa o ni ṣe bẹẹ mọ."

Oríṣun àwòrán, Jingle Hobama TV
Inu idunnu ati ayọ ni awọn ololufẹ mejeji ọhun fi pari ija wọn loju gbogbo awọn eeyan to peju sibi ipade naa, ti wọn si tun fi ẹnu ko ara wọn lẹnu.
Ki lo ti kọkọ ṣẹlẹ?
Bi ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni Wolii Kasali ti kọkọ sọ oriṣiriṣi ọrọ nipa iyawo rẹ naa lẹyin ti aarin wọn daru.
Lara awọn awọn ohun to sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba ni bi ija ṣe waye laarin wọn, ohun to ṣokunfa ija naa ati bi oun ṣe ni iyawo keji.
Lẹyin ija to waye laarin awọn mejeeji ni Kasali fẹ iyawo miran, iyẹn orekelẹwa, Dolapo Awosika.
- Wọ́n ti tú akọ̀ròyìn BBC, Girmay Gebru sílẹ̀ kúrò látìmọ́lé ní Tigray
- Ọlọrun má jẹ́ kí a jẹ́ gbèsè lókù báyìí tí a kò kó ọjá lọ sílẹ̀ Yorùbá mọ́- Hausa Oníṣòwò
- Nǹkan dé, Igboho ní káwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá lọ múra ògùn jọ nítorí ohun tó ń bọ̀ lọ́nà
- Ewú ńbẹ! tí ìjọba ìpínlẹ̀ bá sàkóso gbèndéke owó oṣù òṣìṣẹ́,wọ́n ò ní san N30,000, N10,000 ní wọ́n má á san -NLC
- Àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin gbé ní Zamfara fẹ́ yẹ̀yẹ́ Ìjọba Buhari ni- Hadi Sirika
Nigba to n sọrọ ṣaaju nipa iyawo rẹ keji ọhun, Kasali sọ pe oun fẹran iyawo oun akọkọ, iyẹn Bunmi ti wọn ṣẹṣẹ pari ija yii, ati pe kii ṣe oogun ni oun fi de Dolapo mọlẹ gẹgẹ bii ahesọ ọrọ ti awọn kan n gbe kiri.
Nipa Dolapo naa, Kasali ni o jẹ ẹni ti Ọlọrun ran si oun, oun ko si le ju angẹli oun nu.
Lẹyinorẹyin, ija ti pari laarin Wolii Kasali ati aya rẹ akọkọ.
Pupọ awọn ololufẹ Wolii naa lo si ti n ki awọn mejeeji ku oriire igbesẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe ọhun.
Bo tillẹ jẹ pe afọju ni Wolii Kasali, ti wọn si bi i sinu idile Musulumi, ṣugbọn wọn ko bii gẹgẹ bii afọju, o si jẹ ọkan gboogi lara awọn Wolii ti ọpọ eeyan gbagbọ pe agbara Ọlọrun n bẹ pẹlu rẹ lasiko yii.
















