Sadiq Daba biography: Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sadiq Daba 'Inspector Waziri' nínú sinimá October 1 tó jáde láyé rèé

Sadiq Daba

Oríṣun àwòrán, Premium times

Gbajumọ oṣere ni Sadiq Abubakar Daba ti ọpọ mọ si Sadiq Daba. Akọṣẹmọṣẹ igbohunsafẹfẹ si tun ni pẹlu.

Bi o tilẹ jẹ pe ọmọ ilu Kano ni, Ilu Freetown lorilẹede Sierra Leone lo gbe dagba ki o to pada si orilẹede Naijiria nigba to pe ọmọ ọdun marundinlogun.

Ileewe St Edwards Secondary school ni ilu Freetown lo lọ fun ẹkọ girama ki o to lọ gba iwe ẹri imọ ijinlẹ ni fasiti Ahmadu Bello University ni ilu Zaria.

Daba ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbohunsafẹfẹ ni ileeṣẹ mohunmaworan apapọ Naijiria, NTA ki o to bẹrẹ si ni mu iṣẹ ere sinima ati itage mọ iṣẹ rẹ ni nnkan bii ogoji ọdun o le diẹ sẹyin pẹlu ere ọlọsọọsẹ ni " Cockcrow at dawn"

Àkọlé fídíò, Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala

Ni ọdun 2017 ni Daba kede pe oun ti ni aisan jẹjẹrẹ inu ẹjẹ ati jẹjẹrẹ inu koropọn ọmọ ọkunrin.

Lasiko yii, ọpọ awọn eekan ọmọ Naijiria ni wọn dide iranwọ owo fun un nigba naa.

Ni ọjọ kẹta, oṣu kẹta ọdun 2021 ni Sadiq Abubakar Daba dagbere faye ni ileewosan kan ni ilu Eko.

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun