ENDSARS: Báwo ní Ọba Rilwan tí ìlú Eko ṣe ní $2 million àti N17 million sí inú àfin rẹ̀?

Endsars

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ibeere ti awọn eniyan n bi Oba Rilwan lori ẹrọ ayelujara ni wi pe bawọ ni ọba ṣe ni iye owo to to Miliọnu meji dọla owo ilẹ okeere ati miliọnu mẹtadinlogun naira si inu afin rẹ.

Eyi ko ṣẹyin ẹsun ti Ọba ilu Eko, Rilwan Akiolu fikan awn ọdọ Endsars wi pe wọn ji owo ohun ninu afin nigba ifẹhọnuhan Endsars.

Oba Akiolu sọ ọrọ yii lasiko ti wọn ṣi haalu, Glover Memorial Hal, ni agbegbe Custom street, ni Lagos Island, ti wọn jo lasiko ifẹhọnuhan Endsars.

Oba Akiolu ni ti awọn eniyan ba mọ ipalara to wa nipa jiji owo ọba ni, wọn o ni ṣe e, amọ ohun ko ni sepe fun wọn.

Lara awọn ọdọ n kesi Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lawujọ lati ṣewadii bi ọba ṣe ni iye owo to to bẹẹ si ile.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Amọ, awọn miran ni awọn ọba ni ilẹ Yoruba ma n ni ọrọ nitori iru eniyan ti wọn jẹ lawujọ, ati wi pe Oba Rilwan ko lo lowo ju laarin awọn ọba ni ilẹ Yoruba.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Amọ Deji ti ilu Akure, Ọba Aladetoyinbo ni awọn ọba ko ni owo bẹẹ ni wọn ko ni agbara mọ bi ti atẹyinwa, a ti wi pe orukọ nikan ni wọn ni.

Àkọlé fídíò, Fulani-Yoruba Crisis: Oba Soun ló fí mi jẹ ọba Sabo ni Ogbomọṣọ- Alh Haruna Bala Abdulsala