Ọba Rilwan Akiolu: Fídíò kan lórí ayélujára ṣàfihàn Eleko tó ń jó wọ ààfin Iga Iduganran

Oríṣun àwòrán, @Oreoluwa_Finnih
Iroyin kan to n ja rain-rain lori ayelujara lo ni Eleko tilu Eko, Oba Rilwan Akiolu ti pada sinu aafin rẹ to wa ni Iga Iduganran.
Fidio kan to n ja rainrain lori ayelujara, lo fidi eyi mulẹ bi o tilẹ jẹ pe Ọba Akiolu ko tii tẹ atẹjade kankan sita nipa igbesẹ yii.
Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Kọkanlelogun osu Kẹwa ọdun 2020 ni Ọba Akiolu kuro ninu aafin rẹ laarin awọn ẹsọ alaabo to dihamọra.
Isẹlẹ naa si lo waye lasiko ti awọn janduku ẹda kan ya bo aafin Iga Iduganran nilu Eko lasiko rogbodiyan to tẹle iwọde EndSARS.
Lẹyin ti awọn osisẹ alaabo gbe ọba Akiolu kuro ninu aafin naa, ni awọn janduku naa raye sisẹ ibi ọwọ wọn, ti wọn si ko awọn ẹru kan kuro ninu aafin ọhun.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Lara awọn dukia Ọba Akiolu ti wọn ji ko ni ọpa aṣẹ rẹ, bata ọba, ọpọ apo irẹsi atawọn ẹru miran, koda wọn tun ba awọn nnkan mii jẹ nibẹ, paapaa ni ibudo igbalejo ọba naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Iléẹ̀kọ́ Deeper Life, ẹ san N100m owó gbà má bínú fún ọmọ mi, kẹ sì tọrọ àforíjìn - Òbí akẹ́kọ̀ọ́
- Àwọn òṣèré Yorùbá t'Élédùwà gbà fún àmọ́ tí wọn kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ Yorùbá
- Dangote já mi kulẹ̀ lóri ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àmọ́ ó kọ́ mi bá a ṣé lówó - Ọ̀rẹ́bìnrin Dangote lahùn
- Ẹ sunkún mọ níwọ̀n lórí àríwísí yín sí Buhari lọ́dún 2021 - Femi Adesina
- Mọ̀ si nípa Samuel Ajayi Crowther, bó ṣe pé àádóje ọdún tó jáye láyé
- Ọ̀lẹ adàrí, tí kò lóye, ló fìyà jẹ wá ní 2020 yàtọ̀ sí Coronavirus - Atiku Abubakar
Lati igba ti isẹlẹ naa si ti waye, ko si ẹni to le sọ pato ibi ti ọba Akiolu fara pamọ si, ti awuye-wuye si tun n waye nipa ọpa asẹ rẹ tawọn janduku naa ji gbe.
Bakan naa ni ko si ẹni to mọ boya wọn ti da ọpa asẹ ọhun pada.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Amọ lọjọ Ẹti, eyiun ọjọ Kinni osu Kinni ọdun 2021, tii se ọjọ ọdun tuntun, ni fidio kan gba ori ayelujara kan, ninu eyi taa ti ri ọba Akiolu to n jo wọnu aafin rẹ lọ.
Ọba naa, ti ọpọ ọdọ rọgba yi ka lo pa kaja aọ Saki funfun lai wọ buba kankan sori rẹ, o de fila asọ funfun, wọ bata funfun, to si mu ọpa kan lọwọ.
Bakan naa ni ọba Akiolu lo ibomu funfun gẹgẹ bi ara ilana to n dena itankalẹ arun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Awọn onilu dundun ati Sẹkẹrẹ ni wọn n kan ilu si Kabiesi nibadi, toun naa si njo si ilu naa eyi to ni ' Esuru se aseju, o tẹ lọwọ oniyan.'
Bi Ọba Eleko si se n jo, naa lo n fi ẹsẹ rin lọ sinu aafin, ti ọpọ eeyan to wa nibẹ naa si n sa a ni mẹsan-mẹwaa, bẹẹ ni wsn n ba jo pẹlu.
Bi o tilẹ jẹ pe a ko tii fidi rẹ mulẹ boya lootọ ni Kabiesi ti wa ninu aafin Iga Iduganran, amọ iwadii si n lọ lọwọ lori rẹ, eyi ta mu wa fun yin laipẹ.

Oríṣun àwòrán, LASG and Screenshot
Amọ ọrọ kan ti amugbalẹ́gbẹ́ gomina ipinlẹ́ Eko feto ilera, Oreoluwa Finnih kọ soju opo Twitter rẹ lo fidi isẹlẹ naa mulẹ, pẹlu fidio ọ̀hun to gbe soju opo naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Akọle to kọ sabẹ fidio naa ni pe ' Ọba tilu Eko, Alayeluwa Ọba Rilwan Babatunde Osuolale Aremu Akiolu fi ọla nla wọ aafin Iduganran lọjọ Ẹti,, ọjọ Kinni, osu Kinni ọdun 2021.















