Femi Adesina: Ààrẹ Buhari ti gbìyànjú tó, ẹ sinmi agbaja àti ìbàjẹ́ rẹ̀

Aworan aarẹ Buhari ati Femi Adesina

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Adesina

Oludamọran pataki fun aarẹ Buhari lori eto iroyin ati ikede, Femi Adesina, ti sọ oko ọrọ si awọn to n bu ẹnu ẹtẹ lu aarẹ, o ni ki wọn din ẹkun sisun wọn ku lọdun 2021.

Ninu ọrọ apilẹkọ rẹ to fi sita, Adesina sọ pe ẹlẹkun ni awọn to n bu aarẹ Buhari nitori pe wọn kudun lati ma a bu titi de ori nkan ti ko ni itumọ.

Femi Adesina sọ pe ọdun iṣẹ aṣekara ni 2021 jẹ, ki ijọba le ṣayeyọri lori awọn akaṣe iṣẹ to dawọ le.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ọdun to yẹ lati sinmi agbaja ni, to yẹ ki awọn ẹlẹkun to n ṣe ibajẹ aarẹ wa iṣẹ ṣe, ki wọn o le fi aaye gba ijọba lati gbajumọ iṣẹ to wa lọwọ rẹ."

Àkọlé fídíò, Adejare Adeboye: Olúwa yóò dá gbogbo ohun ta sọnù ní 2020 padà ní ilọ́po méje fún wa

O tẹsiwaju pe ẹnikẹni to ba nifẹ orilẹ-ede Naijiria, gbọdọ pinnu lati mase di ijọba lọwọ lọdun yii.

O ni lootọ ni ipenija wa lori eto aabo, ọrọ aje, airiṣẹ ṣe, ati awọn nkan mii. Ṣugbọn o yẹ ki wọn ma a yin ijọba ni, ki wọn o si mu ori rẹ wu lati ṣe daadaa si.

"Ọpọlọpọ awọn ti ko mọ riri isẹ Buhari, lo n jẹ anfaani aṣeyọri ijọba rẹ, pẹlu bi awọn kan lara wọn sẹ n wọ ọkọ oju'rin ti iṣakoso rẹ filọlẹ."

Àkọlé fídíò, Èmi nìkàn kọ́ ni mó n ṣe àkójọ orin- Fasoyin

Adesina ni kii ṣe pe oun ni ki wọn o ma bu ẹnu ẹtẹ lu aarẹ lọdun 2021, amọ ko gbọdọ jẹ koko iṣẹ ti wọn yan layo.

O ni bi nkan ṣe buru to fun Naijiria lori eto ọrọ aje, owo oṣu awọn oṣisẹ ati awọn to ti fẹhinti, to fi mọ ipese owo fun nkan amayedẹrun ati iṣẹ agbẹ ko dawọ duro, nitori aṣẹ ti Buhari pa fun minisita fun eto inawo.

"To ba jẹ awọn ijọba asiko kan ni, apo ara wọn ni wọn o da iwọnba owo to wa nilẹ si."