Leah Sharibu: Ẹbí ní ìjọba Buhari kò ní àwáwí láti máṣe gba ìdáǹdè akẹ́kọ̀ọ́bìnrin náà

Leah Sharibu ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, @Frank_Obiora

Iya to bi Leah Sharibu, ọmọbinrin ti Boko Haram ji gbe lati ọdun meji le diẹ sẹyin, ti dubulẹ aisan lọjọ Keresimesi, to si ti n gba itọju nile iwosan.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ Kakandinlogun osu Keji ọdun 2018 ni Boko Haram ji akẹkọbinrin aadọfa ko lọ nile ẹkọ girama obinrin to wa nilu Dapci nipinlẹ Yobe.

Bi o tilẹ jẹ pe Boko Haram fun awọn akẹkọọ yoku nidande amọ Leah Sharibu, tii se ọmọ ọdun mẹrinla nigba naa, nikan ni wọn ko tu silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ti sọ, igba akọkọ kọ ree ti iya Leah yoo wolẹ aisan lọjọ ọdun Keresi nitori bo ti se naa ree lọdun 2018 ati 2019.

Àkọlé fídíò, Adejare Adeboye: Olúwa yóò dá gbogbo ohun ta sọnù ní 2020 padà ní ilọ́po méje fún wa

Agbẹnusọ fun idile naa, Gloria Puldu sisọ loju rẹ pe keresi kẹta ree ti Leah yoo se ni ahamọ ajinigbe.

O wa n rọ ijọba lati se amusẹ ileri rẹ lati gba idande Leah ni ahamọ Boko Haram.

O ni ko si awawi fun ijọba lori bi ko se le gba itusilẹ akẹkọọbinrin naa, niwọn igba to gba idande awọn akẹkọọkunrin Kankara laarin ọjọ mẹfa pere.