Insecurity in Nigeria: Arewa ní owó ìdáǹdè ìjínigbé ni agbébọn fi ń ra ohun ìjà olóró

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Police Force
Ẹgbẹ apapọ awọn ọmọ bibi ẹkun ariwa Naijiria, Arewa, ti n ke gbajare ninu ọdun tuntun lori eto aabo to dojude loke ọya.
Alaga apapọ fẹgbẹ Arewa, Oloye Audu Ogbeh lo ke gbajare bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita.
Ogbeh ni Rakunmi ati lawọn janduku n lo bayii lati gbe awọn ado iku ati ibọn ajabaalu walẹ wọ Naijiria wa, lati awọn ẹnu bode to wa lapa ariwa orilẹede yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bí 2020 ṣe ń lọ sópin, Alapinni Oosa wúre ọdún fún ọmọ Yorùbá
- A ti yí orin ọdún ń lọ sópin sí èdè Igbo àti Hausa - Mama Fasoyin
- Àkójọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó dára àti èyí tó burú tó wáyé ní 2020
- Ẹ wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká ọmọ Nàíjíríà tó jáde láyé lọ́dún 2020
- Wo ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù fóónù tí Whatsapp kò ní bá ṣiṣẹ́ mọ́ lọ́dún 2021
- Ẹ wo àwọn èèkàn eléré ìdárayá tó bá ọdún 2020 lọ
Ninu atẹjade naa to pe akọle rẹ ni 'Awọn ẹnu bode wa ati aifararọ eto aabo', tun sisọ loju rẹ pe lati awọn orilẹede to mule ti Naijiria ni wọn ti n ko awọn ohun ija oloro naa wa.
Ogbeh, ẹni ti ko darukọ awọn orilẹede to mule ti wa naa, wa fikun pe ipinlẹ Sokoto ati Zamfara lawọn ti gbọ nipa iroyin yii, nitori awọn lo ba ilẹ Niger paala.
Alaga ẹgbẹ Arewa naa ni ojuse ẹgbẹ naa ni lati fi ọrọ yi to ijọba apapọ atawọn agbofinro leti, ki wọn le gbe igbesẹ to tọ nitori o n bọ, o n bọ, awọn laa dẹ de.
Bakan naa lo sisọ loju rẹ pe, owo ti awọn ajinigbe naa ba gba lọwọ mọlẹbi ẹni ti wọn mu nigbekun, ni wọn fi n ra awọn ohun ija oloro naa.
O wa parọwa pe kawọn agbofinro maa bẹrẹ si yẹ ara awọn Rakunmi to n wọ ẹnu bode wa wo finnifinni, nitori eyi yoo se ilẹ Naijiria loore pupọ.
Ẹgbẹ Arewa wa n kọminu pe iye awọn agbegbọn yii lo n di pupọ si lojoojumọ, ko si ni pẹ ki wọn to ni awọn ohun ija oloro to yanranti lọwọ, ju awọn agbofinro lọ.


















