2020 in Retrospect: Ìjàmbá iná, ilé tó dàwó, ìwọ́de àti àrùn Covid-19 wà lára ìṣẹ̀lẹ̀ 2020

Àkọlé fídíò, 2020 in Retrospect: Ìjàmbá iná, ilé tó dàwó, ìwọ́de àti àrùn Covid-19 wà lára ìṣẹ̀lẹ̀ 2020

Bo se ku ọjọ kan pere ti ọdun 2020 yoo kogba wọle, ta si ki ara wa kaabọ sinu ọdun tuntun, BBC Yoruba bojuwo ẹyin lati wo awọn isẹlẹ manigbagbe to waye ninu ọdun naa.

Gẹgẹ baa se mọ pe tibi-tire la dale aye, tibi-tire la sẹda eeyan, bẹẹ gẹgẹ naa ni tawọn isẹlẹ manigbagbe yii, ti wọn jẹ ire ati ibi.

Bi o tilẹ jẹ pe isẹlẹ ayọ ko to nnkan, amọ awọn isẹlẹ ibi pọ lọ jaburata bii ijamba ina, ọpọ ile to dawo lulẹ, ijinigbe, aifararọ eto aabo, omiyale ati ọpọ iwọde lorisirisi.

Ẹnu ko gba iroyin lawọn isẹlẹ yii, ẹ sa wo fidio yii lati mọ si nipa awọn isẹlẹ ati iroyin to kasiara lọdun 2020.

A ku oju lọna ọdun tuntun.