Deeper Life: Deeper Life High School ti sọ̀rọ̀ lórí ibi tí nkan dé nípa ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ipá bá lòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter
Awọn alaṣẹ ileewe Deeper Life High School, to jẹ ti ijọ Deeper Life Bible Church, ti fi atẹjade sita, lori ibi ti iwadii de nipa akẹkọọkunrin ti wọn fi ipa balopọ ni ẹka ileewe naa nipinlẹ Akwa Ibom.
Ọmọ ọdun mọkanla ni, to si wa ni kilaasi akọkọ JSS1 nileewe girama naa.
Iya rẹ, Deborah Okezie lo fi fidio kan sita ni ọsẹ to kọja, nibi to ti fi ẹsun kan pe awọn akẹkọọkunrin kan to wa ni kilaasi Agba fi ipa ba ọmọ oun ni ibalopọ, lai ti ju oṣu meji to de ileewe naa lọ.
Thelma Malaka, Akọwe eto ẹkọ nileewe girama naa sọ ninu fidio kan ti ijọ naa fi sita gẹgẹ bi atẹjade loju opo Instagram rẹ pe ọfiisi gomina ipinlẹ Akwa Ibom ti gbakoso iwadii lori isẹlẹ naa, ki akoyawọ le wa.
O ni " a dupẹ lọwọ gbogbo awọn to ti ṣe akitiyan lori ọrọ yii.
"A si tun n sọ pe ao mu ki iwadii ati abajade rẹ han si gbogbo ara ilu."
Arabinrin Malaka sọ pe awọn dẹkun lati sọ ohunkohun lori ọrọ naa, nitori pe awọn wo o pe ko bojumu lati ma a sọrọ lori iṣẹlẹ ti iwadii n lọ lori rẹ.
O ni ṣugbọn bi epo ti didakẹ awọn le ta si aṣọ ala awọn lara lo mu ki awọn pada fi atẹjade tuntun yii sita.
"Igbimọ oluwadii ti joko sẹ ipade, a si ti ko gbogbo awọn oṣiṣẹ ati akẹkọọ ti wọn darukọ wọn ninu iṣẹlẹ naa lọ siwaju wọn ni gbogbo asiko ti iwadii fi n lọ.
"A ni igbagbọ pe ijọba yoo gbe abajade iwadii jade fun ara ilu ni kete to ba pari.
O fikun ọrọ rẹ pe awọn yoo tẹsiwaju lati ṣe atilẹyin fun ọmọ naa, bi awọn obi rẹ ba ṣe faaye gba wọn si.
O ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa naa n ṣe iwadii, ati pe ileewe Deeper Life High School ti sọ nkan to mọ nipa iṣẹlẹ naa.
O ni ki awọn araalu fojusọna fun abajade iwadii ti awọn alaṣẹ yoo gbe jade laipẹ.












