Omoyele Sowore: Ẹyin ọ̀dọ́, ẹ jáde wá ṣe ìwọ́de àìṣùn ọdún láti tako ìjọba burúkú

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore
Iroyin kan to gba ori ayelujara kan lo n wipe awọn agbofinro tun ti mu asiwaju ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni Revolution Now, Omoyele Sowore si ahamọ.
Sowore atawọn ọmọ ẹgbẹ ajafẹtọ ẹni naa ni wọn se iwọde kan to pe akori rẹ ni 'Resolute 2021', bẹrẹ ni alẹ aisun ọdun titi wọnu ọdun tuntun.
- Ọlọ́pàá àti àwọn olùfẹ̀hónúhàn gbéná wojú ara wọn níbi ìwọ́de Revolution Now
- Ìwọ́de #RevolutionNow forí ṣánpọ́n ní Ibadan, àgbófinró gbàkóso ojú pópó
- Sowore àti àwọn ọmọ ẹgbẹ Revolution Now kò ṣẹ̀ ṣófin lórí ìwọ́de, ẹ tú wọn sílẹ̀ - NLC
- Ẹ san ₦200,000 fún Sowore lórí bí ẹ ṣe ń fi ẹjọ́ falẹ̀ - Iléẹjọ́ pàṣẹ fún ìjọba
- ‘Kò sí ohun tó lè yẹ ìfèhọnú ọjọ karun un Oṣu Kẹsan lórí àtìmọ́lé Omoyele Sowore’
Bakan naa tun ni irufẹ iwọde naa tun waye lawọn ipinlẹ kan lorilẹede yii bii Ondo, Kaduna ati Osun mọjumọ ọjọ ọdun tuntun 2021.

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore
Saaju ni alẹ ọjọ aisun ọdun tuntun ni Sowore ti kede loju opo Twitter rẹ pe ki ẹnikẹni to ba nifẹ lati kopa ninu aisun iwọde naa, jade sita .
O ni ki awọn oluwọde ọhun mu abẹla ati paali ikede lọwọ, eyi to n sọ awọn ohun ti wọn n fi ehonu han le lori nipa ijọba Muhammadu Buhari.

Oríṣun àwòrán, @YeleSowore
Bakan naa lo n rọ wọn pe ki wọn pin awọn aworan ati fidio ti wọn ba ya lasiko iwọde naa soju opo ayelujara wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ táwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run sọ nípa ọdún 2021
- Àwọn kókó tó jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ ọdún tí Buhari bá ọmọ Naijiria sọ
- Gbogbo ọjọ́ kérésì ni ìyá Leah Sharibu ń sàìsàn, ó tún ti wà nílé ìwòsàn
- Gbàjarè! Ràkúnmí làwọn agbébọn ń lò láti gbé àdó ikú wọ òkè ọya - Arewa figbe ta
- Bí 2020 ṣe ń lọ sópin, Alapinni Oosa wúre ọdún fún ọmọ Yorùbá
- A ti yí orin ọdún ń lọ sópin sí èdè Igbo àti Hausa - Mama Fasoyin
- Àkójọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó dára àti èyí tó burú tó wáyé ní 2020
- Ẹ wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká ọmọ Nàíjíríà tó jáde láyé lọ́dún 2020
- Wo ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù fóónù tí Whatsapp kò ní bá ṣiṣẹ́ mọ́ lọ́dún 2021
- Ẹ wo àwọn èèkàn eléré ìdárayá tó bá ọdún 2020 lọ
Gẹgẹ ba se gbọ, awọn agbofinro ko jẹ ki iwọde naa tutu, ti wọn fi sẹburu adari iwọde naa nilu Abuja atawọn oluwọde miran, ti wọn si gbe wọn lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ.
Nibayi ọmọ Naijiria lo ti wa n kesi aarẹ Muhammadu Buhari lori ayelujara pe ko tu Omoyele Sowore silẹ ni ahamọ, ko si ye lo ọlọpaa lati dunkoo mọ araalu.















