Ibrahim Babangida: Mo rọ àwọn adarí wa láti jẹ́ àwòkaṣẹ́ rere fún aráàlú

Ibrahim Babangida

Oríṣun àwòrán, Twitter

Adari ijọba ologun lorilẹede Niajiria tẹlẹri, ajagunfẹyinti Ibrahim Babangida ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati ṣe suuru lori eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ, eto ilera ati ebo aabo to mẹhẹ.

Ọgagun Babangida to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ, ni ki wọn ranti pe, ko si ohun to ni ibẹrẹ ti ko lopin.

O ni ọdun 2020 wa pẹlu iṣoro ati awọn idojukọ to lera fun ọpọlọpọ eniyan ti kii ṣe Naijiria nikan, sugbọn kaakiri agbaye ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

'' Ohun to ṣẹlẹ si orilẹede Naiijiria ni ọdun 2020 kii ṣe si awa nikan, nitori arun Coronavirus naa ṣi n ja ranyin lagbaye, titi di wakati yii.

Àkọlé fídíò, Oluwo Jogbodo Orunmila: Ẹsẹ odù Ifa ló fi ṣúre fún ọmọ Nàíjíríà ní àyájọ́ ọdún tuntun

Nitori naa, gbogbo ẹkọ ti ẹ kọ ni ọdun 2020, ẹ gbọdọ mu lo ninu ọdun tuntun naa, ki o ma ba lọ lasan.

A rọ awọn eniyan lati mọ wi pe, idojukọ to lagbara ni arun Coronavirus, amọ ki wọn mu ni okunkundun, ki wọn le bori arun naa ni kiakia''

Bakan naa ni Babangida wa rọ awọn adari ni Naijiria lati jẹ awokọṣe fun awọn eniyan ti wọn jẹ adari fun.

Àkọlé fídíò, Adejare Adeboye: Olúwa yóò dá gbogbo ohun ta sọnù ní 2020 padà ní ilọ́po méje fún wa

Babangida ni ohun to buru jai ni ki aarẹ orilẹede kọ lati ba awọn ara ilu sọrọ lasiko ti nkan gbona janjan lara awọn eniyan.

Adari tẹlẹ fun ijọba ologun naa wa parọwa si awọn ọmọ Naijiria lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba, lati fopin si eto aabo to dẹnukọlẹ.

Ọ̀lẹ adàrí, tí kò lóye, ló fìyà jẹ wá ní 2020 yàtọ̀ sí Coronavirus - Atiku Abubakar

Igbakeji aarẹ lorilẹede Naijiria tẹlẹri, Atiku Abubakar ti sọ wi pe, kii ṣe arun Coronavirus nikan lo n ba Naijiria ja ni ọdun to kọja, amọ awọn adari ti ko ni imọ, ti wọn si tun ya ọlẹ, lo fi iya jẹ awọn ọmọ Naijiria.

Atiku Abubakar

Atiku Abubakar sọ eyi ninu isẹ ikini ku ọdun tuntun to fi ranṣẹ si awọn ọmọ Naijiria, ninu eyi to ti fi ariwirisi rẹ lede fun araye gbọ.

Atiku ni bi o tilẹ jẹ pe arun Coronavirus ba awọn eniyan finra lootọ, amọ ṣeni laanu pe ọpọlọpọ iṣoro naa lo duro ti awọn ọmọ Naijiria bii ajakalẹ arun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa kesi awọn ọmọ Naijiria lati fọwọsowọpọ lati gbogun ti iwa jẹgudujẹra, igbesunmọmi ati awọn iwa ọdaran to ba awọn eniyan ja lorilẹede Naijiria, to fi mọ ọrọ aje to dẹnukọlẹ lorilẹede Naijiria.

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, AFP

Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2019 naa wa rọ awọn eniyan, lati lo iṣọkan ti wọn gba laye lati gbogun ti arun Coronavirus naa, lati wa ọna abayọ si ipenija to n koju awọn ọmọ Naijiria.

''Pẹlu ayọ ni mo ki yin kaabọ si ọdun tuntun, ọdun 2021, ẹ si ku alaja ọdun to kọja to kun fun ibanujẹ ati irora''

''Bi a ti n wọ inu ọdun tuntun naa, mo ni igbagbọ pe arun Covid-19 naa yoo di ohun afiṣẹyin ti eegun fisọ, ti ko si ni gbooro mọ ni agbaye,''

''Igbagbọ mi ni pe oogun abẹrẹ ajẹsara naa yoo wa fun awọn ọmọ Naijiria laipẹ, eleyii ti yoo mu ki gbogbo agbaye pada si bi o ṣe wa tẹlẹ.''

''Mo gbadura fun ẹbi awọn ti ẹmi wọn ti lọ lati ipasẹ arun Covid-19 pe eedua yoo nu ẹkun wọn nu, ti a si fi ayọ rọpo sibẹ.''

Àkọlé fídíò, Adejare Adeboye: Olúwa yóò dá gbogbo ohun ta sọnù ní 2020 padà ní ilọ́po méje fún wa

''Bakan naa iya ati iṣẹ to n ba awọn ọmọ Naijiria finra niiṣe pẹlu awọn adari ti ko mu eto ọrọ aje munadoko ni Naijiria.''

Atiku Abubakar wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati gba alaafia laaye, ki itẹsiwaju le ba orilẹede Naijiria.