Atiku: Mo lọ Amẹ́ríkà láti sọ̀rọ̀ lórí ètò ìdíkoòwò

Atiku Abubakar ati Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, Bukola Saraki/Twitter

Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye wipe oludije fun ipo Aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ko to ẹni to n lọ orilẹede Amerika tori o ni ẹjọ nibẹ, ni ọjọbọ ni Atiku wọ Amẹrika.

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ naa to tun n dije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP bayii gbe aworan irinajo rẹ si Amẹrika sori ikanni ayelujara Twitter ni alẹ Ọjọbọ wipe oun ti de orilẹede naa bayii.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Aworan naa fi han nibi to ti duro pẹlu Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin Bukola Saraki ti arabinrin kan si n fi adodo kii kaabọ.

O fi ọrọ sori aworan naa pe, " Mo ṣẹṣẹ de si Washinton D.C fun ipade pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba ati awọn ọmọ orilẹede Naijiria to wa ni D.C. ati awọn to n gbe agbegbe idokowo."

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Twitter

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ oṣelu APC ti n fẹsun kan an wipe nitori o ni ẹjọ lọrun ni ko ṣe le lọ orilẹede Amerika

Ti pẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC ti n fẹsun kan an wipe nitori o ni ẹjọ lọrun ni ko ṣe le lọ orilẹede Amerika, ṣugbọn ileeṣẹ aṣoju orilẹede Amẹrika ni Naijria ni awọn ko ni akọsilẹ to fi han wipe Atiku ni ẹjọ lọrun ni orilẹede naa.

Aworan kan naa ti Saraki fi sori Twitter ṣe afihan ibi ti oun ati Saraki ati sẹnetọ Ben Bruce ti n ṣe ipade pẹlu ọmọ ile aṣoju-ṣofin ilẹ Amẹrika, Chris Smith.

Atiku Abubakar, Bukola Saraki ati Ben Bruce ninu ipade kan pẹlu aṣofin ara amẹrika Chris Smith

Oríṣun àwòrán, Bukola Saraki/Twitter