Nigeria Elections 2019:Muhammadu Buhari, olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn bi Aarẹ Muhammadu Buhari ni idile ẹya Fulani kan ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kejila ọdun 1942 ni ilu Daura ipinlẹ Katsina.
Oloye Fulani kan ni baba rẹ jẹ ti orukọ iya rẹ si n jẹ Zulaihat. Oun ni ikẹtalelogun ninu ọmọ baba rẹ.
Lati nkan bi ọmọ ọdun mẹrin lẹyin ti baba rẹ ku ni iya Buhari ti n tọ ọ titi ti o fi dagba.
Muhammadu Buhari jẹ oloṣelu a si le ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn gbajugbaja oloṣelu tẹsẹ wọn rinlẹ ni iha Ariwa orilẹede Naijiria.
Ilé Ìwé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọmọ ọdun mọkandinlogun, Buhari dara pọ mọ ile iwe girama fun ẹkọ nipa ijagun, Nigerian Military Training College (NMTC) ni odun 1962. Ni oṣu keji ọdun 1964, wọn sọ ile iwe girama ọhun di ẹka ile iṣẹ ologun to laṣẹ lati sọ ni di ọmọ ogun alakọbẹrẹ wọn si sọ orukọ rẹ di ile ẹkọ awọn ọmọ ogun alaabo, Nigerian Defence Academy (NDA).
Ṣaaju eyi, Buhari lọ fun imọ ẹkọ Cadet ni ile iwe Mons Officer Cadet School, Aldertson ni ilẹ Gẹẹsi laarin ọdun 1962 si 1963.

Oríṣun àwòrán, @ArewaHistory
Ni ọdun 1963 nigba to pe ogun ọdun, Buhari gba oye second liutenant wọn si fi jẹ adari ikọ ogun Second Infantry Battalion ni ilu Abeokuta. Bakan naa, o kọ ẹkọ sii ni Nigeria Military Training College, Kaduna laarin oṣu kọkanla dun 1963 si oṣu kinni ọdun 1964. O fi kun imọ ẹkọ rẹ ni Army Mechanincal Transport School, Borden ni ilẹ United Kingdom. Lẹyin eyi, ọpọlọpọ iwe lo ti ka kun un.
Laarin ọdun 1965 si 1967, Buhari ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọgagun Second Infantry Battalion wọn si fi jẹ oye brigade major ti Second Sector, First Infantry Division ni osu kẹrin si ikeje ọdun 1967. Bakan naa o lọ si ile iwe awọn ọmọ ogun alaabo ti Defence Services Staff College, Wellington ni India lọdun 1973.

Oríṣun àwòrán, @DeeOneAyekooto
Gẹgẹ bi Colonel, Buhari lọ si ile iwe girama US Army ni Carlisle ni Pennyslvania nibi ti o ti gba oye oni ipele keji Masters Degree ninu ẹkọ Stategic Studies.
Muhammadu Buhari ti kopa ribiribi lasiko ogun fun Naijiria.
Bakan naa o ti ba wọn kopa ninu gbigbogun ti isẹlẹ pipa awọn adari orilẹede Naijiria.
Awọn mii to mọ si iṣẹlẹ ọhun ni Ọgagun Sanni Abacha, Ọgagun Ibrahim Babangida.
Lati ọdun 1970 si 1971, Buhari jẹ Ọgagun gẹgẹ bi Major Commandant fun ikọ ogun Thirty-first Infantry Brigade. O tun wa jẹ igbakeji Adjutant-General ti olu ile iṣẹ First Infantry Division lati 1971 si 1972.
Bakan naa, o jẹ adele adari ẹka irina ni olu ile iṣẹ ogun Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Laarin ọjọ Kinni Oṣu kẹjọ ọdun 1975 si ọjọ Kẹta Oṣu keji ọdun 1976, Ọgagun Murtala Muhammed yan Buhari gẹgẹ bi Gomina awọn ipinlẹ ila Oorun Ariwa papọ ti pe ni North-Eastern States nigba naa lọhun. Bakan naa ni ranpẹ, Buhari ṣe Gomina ipinlẹ Borno lati ọjọ Kẹta Oṣu keji ọdun 1976 si ọjọ ikẹẹdogun oṣu Kẹta ọdun 1976.
Ni ọjọ Kẹta Oṣu keji ọdun 1976 ijọba ologun pin awọn ipinlẹ Ariwa yii si Bauchi, Borno ati ipinlẹ Gongola. Ni oṣu kẹjọ ọdun 1991, wọn ya ipinlẹ Yobe latara Borno nigba ti wọn pin ipinlẹ Gongola si meji, Taraba ati Adamawa. Ni Oṣu kẹwaa, wọn da ipinlẹ Gombe silẹ latara Bauchi.
Akoko mii ti ko ṣee gbagbe ninu ipa rẹ ni igba to dari awọn ọmoogun Naijiria lati koju awọn ọmọogun Chad to ya wọ ipinl Borno lọdun 1983.
Ni ọdun 1983 si 1985, Ọgagun agba Muhammadu Buhari pẹlu igbakeji rẹ, Oloogbe Ọgagun agba Tunde Idiagbọn k'ara bọ yiyọ awọn awọn oloṣelu kan ti wọn si dojukọ gbogbo iwa ibajẹ ti gbongbo ti gbongbo.
Wọnyii ni awọn ipo mii ti Aarẹ Buhari ti di mu latẹyin wa
- Kọmisana fun ọrọ epo bẹntiroolu ati ohun alumọni abẹ omi - Oṣu kẹta, 1976
- Alaga ile iṣẹ ipọnpo NNPC - 1977 titi di 1978
- Akọwe olu ile iṣẹ ogun - 1978 titi di 1979

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin igba mẹta to ti gbiyanju lati dupo Aarẹ lọdun 2003, 2007 ati 2011, Buhari tun gbiyanju lẹlẹẹkẹrin lọdun 2015 labẹ Asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress to si fidi Aarẹ to wa lori alefa nigba naa, Goodluck Jonathan ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party janlẹ - o jẹ igba akọkọ ti Aarẹ to wa lori oye yoo padanu rẹ ninu idibo.
Buhari wa di gbajumọ ẹgbẹ oṣelu alatako lakọkọ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Nigeria People's Party (ANPP) lẹyin naa, Congress for Progressive Change (CPC) ati All Progressives Congress (APC).
Gẹgẹ bi oludije fun ipo Aarẹ lati ibẹrẹ wá lo ti ni awọn igbakeji yii:
- Ọmọwe Chuba Okadigbo (2003)
- Edwin Ume-Ezeoke (2007)
- Pásítọ̀ Tunde Bakare (2011)
- Ọjọgbọn Yemi Osinbajo (2015)
Idibo ti ọdun 2015 jẹ eyi to laami laaka gẹgẹ bi Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ Ọjọgbọn Yemi Oṣinbajo ṣe polongo pẹlu ileri 'ayipada' ni ibo to le ni miliọnu mẹẹdogun lati jawe olubori ninu idibo naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ gbegba oroke pẹlu ifarajin lati koju iwa ajẹbanu, airiṣẹ ati iṣoro aabo.
Ijọba rẹ gbagbọ pe awọn ti bori ikọlu Boko Haram ni iha Ila Oorun Ariwa ṣugbọn eyi ti wa di ọna adọgbn kọlu ẹgbẹ ati awọn eniyan agbegbe naa.
Iṣẹlẹ bí àwọn Fulani daran daran ṣe n paniyan, jiji akẹkọọ to le lọgọrun un gbe nile iwe ijọba Dapchi, ipinlẹ Yobe wa lara ipenija ti ijọba Aarẹ Buhari n doju kọ lagbegbe naa.
Aarẹ Buhari koju ipenija ninu ibaṣepọ rẹ pẹlu ile igbimọ aṣofin lori ọrọ iyanni sipo ati ilana aba eto isuna, ati bẹẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi idibo ọdun 2019 ṣe balẹ biba, Aarẹ Buhari n ja fita fita lati dupo yii lẹẹkan sii. Nida miiran ẹwẹ, awọn ẹgbẹ oṣelu miiran n fẹ ko fi ipo silẹ ko lọ simi bo ba ti pari saa akọkọ rẹ.
Ẹni ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bi ọkunrin olootọ, olufọkansin ati onigbagbọ gidi ninu isọkan Naijiria, ajọ isọkan ilẹ Afirika fun un ni ami idalọla wọn si gbe iṣẹ didari ipolongo lodi si iwa ajẹbanu nilẹ Afirika.
O gba oye Grand Commander of the Fedral Republic (GCFR) ati ọpọlọpọ oye idalọla mii.
Aarẹ Muhammadu Buhari fẹ Aisha Muhammadu Buhari to j obinrin akọkọ ni Naijiria, Ọlọrun si fi ọmọ ati ọmọ ọmọ ta wọn lọrẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
#BBCNigeria2019












