Atiku Abubakar - Kò dájú pé ìdìbò 2019 yóò kẹ́sẹjárí

Oríṣun àwòrán, REUTERS/Temilade Adelaja
Bi idibo ọdun 2019 lorileede Naijiria ti ṣe ku osu kan, oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, ti sọ fun BBC pe oun ko ni igbagbọ pe eto ibo naa ko ni ni mago mago ninu.
Atiku Abubakar to jẹ ọmọ ọdun mẹ́rìnléláàdọ́rin to si dipo igbakeji aarẹ mu rlaarin ọdun 1999 si 2007 ni awọn eeyan gbagbọ pe oun ni alatako gboogi ti Aarẹ Buhari ni.
Nigba ti akọroyin BBC bere lọwọ rẹ pe se yoo gba ni irọwọrọsẹ ti o ba fidirẹmi ninu idibo naa, Atiku sọ pe o da oun loju pe oun ko ni fidirẹmi.
''Ki ṣe ọrọ boya maa fidirẹmi lo delẹ yi, ohun to ṣe pataki julọ ni boya idibo yi ko ni ni mago mago ninu.
Pẹlu gbogbo igbesẹ ti ẹgbẹ oṣelu to wa nijọba n gbe, ti a si ti ri, ko si aridaju pe wọn ṣetan lati ṣeto idibo ti yoo kẹsẹ jari''
Atiku ni ohun to ṣẹlẹ ninu awọn atundi ibo to ti waye labẹ iṣakoso ẹgbẹ APC to ṣafihan bi APC ṣe fi awọn agbofinro dun kukulaja mọ awọn oludibo n tọka si ohun ti oun n sọ.
''A n parọwa si awọn awujọ agbaye lati gbaruku ti wa ki eto idibo yi lọ ni irọwọrọsẹ''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lori ọrọ pe ko fẹ ẹ si iyatọ laarin ẹgbẹ oṣelu rẹ, PDP ati ẹgbẹ oṣelu APC nipa afojusun wọn ati bi wọn ṣe n ṣe ipolongo ibo ti ko gbajumọ ọrọ to ṣe koko, Atiku ni iru nkan bẹ ko le ṣai waye nitori pe eto oṣelu Naijiria ko ti fẹsẹ rinlẹ daada.

Kini eero rẹ lori ki awọn ọdọ o ṣe ijọba?
''Mi o ṣe idiwọ fun ọdọ to ba fẹ du ipo. Mi o si lero wi pe o tọ lati ma dẹyẹ si mi nitori ọjọ ori mi''
Bakan naa ni Atiku, ninu ibeere mi to jẹyọ lori eto aabo ṣalaye bi yoo ti ṣe dari ipenija to n koju awọn ọmọ ileeṣẹ ologun Naijria.
O ni ẹbi bi nkan ṣe ri ki ṣe awọn ileeṣẹ ologun nikan.
"Mo lero wi pe apapọ awọn ọmọ ogun ni wọn ko gbiyanju to. O jọ bi ẹni pe o ti rẹ wọn.
Ati ọmọ ogun ofurufu ati t'oriilẹ, wọn ti pẹ nibẹ ti eleyi si n ṣe ifasẹyin fun wọ."












