IG Police: Ààrẹ Buhari yan Adamu Mohammed ladelé ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjírìa

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmad
Adele ọga ọlọpaa tuntun lorileede Naijiria,Adamu Mohammed ti pinu lati mu atunto ba eto aabọ ni Naijiria.
Adamu ṣeleri yi nigba ti o n ba awọn akoroyin sọrọ nilejọba labuja ni kete ti o ṣe ipade tan pẹlu aarẹ Buhari.
Ninu esi rẹ, o ni ipenija aabo jẹ ohun to j ohun logun lati kọju toun ti bi ijinigbe,ikọlu ati awọn iwa janduku miran ti ṣe gbode .

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmad
Adamu sọ pe gbogbo eto ti ẹni to fi ipo silẹ saaju ohun mulo ni ohun naa yoo tele lati ri wi pe ọhun gbogbo nkan lọ ni irọwọrọsẹ ni Naijiria.
Lọjọ iṣẹgun ti ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria Ibrahim Idris fẹyinti lẹnu iṣẹ ọba ni Muhammed gun ori ipo naa.
Ipenija ti o wa ni iwaju Adamu
Adamu yoo ni awọn ipenija lati koju paapa julọ lori idibo ọdun 2019 to de tan.

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmad
Bakannaa ni yoo ni lati wa wọrọko fi sada lori ohun ti awọn ẹgbẹ alatako n sọ paapa julọ nipa bi ileeṣẹ ọlọpaa labẹ ẹni to fi ipo naa silẹ, Ibrahim Idris ti ṣe n dun kukulaja mọ awọn
''Mi o ni dẹyẹ si ẹnikankan ma si ri wipe a tẹle ohun ti ọfin ba sọ'' ni ohun ti Adamu fẹsi nipa iṣedeede laarin gbogbo ẹgb oṣelu.
Awọn ohun mi to ti ṣẹlẹ lọjọ ti Adamu gba ipo
Awọn kan ti kọkọ ro wi pe ijọba apapọ yoo fi kun akoko ti ọga ọlọpaa Ibrahim Idris yoo lo lẹnu iṣẹ nitori igbaradi eto aabo fun idibo gbogbogbo ọdun yii.
Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹ ti Ibrahim Idris ati adele rẹ ti jọ ṣe ipade pẹlu Aarẹ Buhari nile ijọba ki Idris to tọwọbọ iwe ni afihan idagbere ati iwọle sipo adele ree tuntun.

Oríṣun àwòrán, @bASIR aHMAD
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O yé ki Aarẹ Muhammadu Buhari kede adele ọga ọlọpaa miran ki o to digba ti ajọ to n risi ọrọ ọlọpaa buwọ lu iyansipo rẹ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọga ọlọpaa Idris wa nile iṣẹ aarẹ lọjọ Aje nibi to ti ṣepade idakọkọ pẹlu Aarẹ Buhari.

Oríṣun àwòrán, @Bashir Ahmad
Ti ọga ọlọpaa Idris ba fẹyinti loni, Abubakar Adamu Mohammed ni a gbọ pe Aarẹ Buhari yoo kede gẹgẹ bi ọga ọlọpaa tuntun.
Ọgbẹni Mohammed jẹ igbakeji ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria, o si jẹ ọmọ ilu Lafia to jẹ olu ilu Ipinlẹ Nasarawa.

Oríṣun àwòrán, @bASIR aHMAD
Ọjọ kẹsan oṣu kọkanla ni wọn bi ọga ọlọpa, lọdun 1986 lo si wọ iṣẹ ọlọpaa.
Ọgbẹni Mohammed gba oye akọkọ nile ẹkọ giga fasiti ninu ẹkọ nipa ile aye(Geography).
O ti figba ri jẹ oludari awọn ọlọpaa to n pẹtu sija, bẹẹ lo si ṣiṣẹ gẹgẹ ọga ọlọpaa nipinlẹ Enugu ki o to di igbakeji ọga ọlọpaa lorilẹede Naijiria.
Ẹka ile iṣẹ ọlọpaa to wa ni ilu Kuru ni Ipinlẹ Plateau ni ọgbẹni Mohammed ti n ṣiṣẹ lọwọ yii.

















