Ẹlẹ́sìn Aghoris: Wọ́n ń jẹ ènìyàn, wọn a sì fi orí rẹ̀ mumi

Aghoris

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Awọn ẹlẹsin Aghoris ma n jade lasiko ọdun Kunbh Mela

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń tẹ̀lẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n bá òkú lòpò yíí, tí wọ́n sì ń jẹ ẹran ara ènìyàn.

Awọn ẹlẹsin Hindu yii ma n woye bii nkan yoo ṣeri pẹlu arojinlẹ,ti wọn si maa n jẹun, sun ati ni ibalopo laarin awọn oku ti wọn n jo ni ina ni itẹ iboji.

Awọn wọnyii maa n rin kaakiri lai wọ asọ, wọn maa n jẹ ẹran ara eniyan ti wọn a si ma a fi agbari eniyan ṣe igba imumi ati ti ounjẹ, ati pe oogun oloro marijuana ki n wọ́n lọwọ wọn lasiko naa.

Àkọlé fídíò, Eko Akete yóò gbàlejò BBC Yoruba
Àkọlé fídíò, Oduduwa Alphabet: òmìnira èdè ti dé fún Port Novo báyìí

Asiko ọdun iwẹ awọ̀n elesin Aghoris nikan ni wọn máa n jade ni Ọjọ Kẹẹdogun, osu kini, odun ni orilẹ-ede India ti wọn n pe ni ọdun Kumbh Mela.

Varanasi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iboji ni awọn ẹlẹsin Agoris ma n lọ si julọ.

Ọ̀pọlọpọ̀ eniyan lo n tẹle awọn okunrin ti wọn ba oku lọpọ yii, ti wọn si n jẹ ẹran ara eniyan.

Aghori

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Ẹlẹsin Aghori to gbe ori eniyan dani

Ni ede Sanskrit, ohun ti orukọ Aghori duro fun ni ‘ẹni ti ki n ba eniyan lẹru’, amọ awọn ohun ti o n banilẹru ti wọn n gbọ nipa wọn maa n fa ibẹrubojo ati irira nipa wọn fun awọn eniyan.

Aghori

Oríṣun àwòrán, Empics

Àkọlé àwòrán, O soro fun awọn ara ita lati gbe pelu awọn ẹlẹsin wọn yii

Ohun to yẹ ko o mọ nipa awọn ẹlẹsin Aghoris ni India

  • Ihuwasi wọn da bi ẹni wi pe wọn sẹṣẹ bẹrẹ ẹsin naa ni saa nkan bii ẹgbẹrun un ọdun mejidinlogun (18th century) sẹyin ni.
  • Ohun ti wọn gbagbọ ni wi pe eniyan ko gbọdọ bẹru iku tabi oku ni wọn se n jẹ eniyan lati bori ibẹru iku.
Aghori

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn eniyan to ba wa si ile India naa ma n lo se abẹwo si awọn elesin Agoris yii
  • Iwadii fihan wi pe awọn ko gbagbo nipa ikorira ọmọlakeji.
  • Awọn ti wọn n se ẹsin yii ko pọ rara. Wọn fikun un pe awọn ti wọn n darapọ mọ ọdun Kumbh Mela kii se awọn ti o jinlẹ ninu ẹsin naa.
Àkọlé fídíò, Sibahle Zwanen fi ìmọ̀ ìṣìro da orí ayélujára rú
Aghoris

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ awọn ẹya Hindu tako igbe aye awọn ẹlẹsin Agoris.
  • Bakan naa ni wọn maa n sisẹ ilu nipa titọju awọn oni warapa ni itẹ ti wọn maa n gbe oku si ati ile iwosan wọn.
  • Amọ wọn korira ibalopọ laarin akọ si akọ, wọn rii gẹgẹ bi ohun irira.
Aghoris

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Eeru lati ara oku ti wọn ti jo nina ni awọn ẹlẹsin Aghoris ma n fi para.
Àkọlé fídíò, Alao Akala:Èmi àti Ajimọbi kò ṣe ìlérí kankan fún ara wa