Asset declaration: Àwọn tó dipò ìlú mú tí wọ́n jẹ́jọ́ lórí dúkìa

Adajọ Walter Onnoghen

Oríṣun àwòrán, NBA

Àkọlé àwòrán, Walter Onnoghen jẹjọ niwaju CCT

Ofin orilẹ-ede Naijiria ni pe ẹnikẹni to ba di ipo ilu mu gbọdọ kede dukia rẹ labẹ ofin Naijiria ko to gori aleefa, bibẹẹkọ ẹni naa yoo foju wina ofin.

Iru nkan yii ti ṣẹlẹ si awọn oloṣelu ati awọn ọga agba kan lẹnu iṣẹ ijọba lorilẹ-ede Naijiria.

Eleyi to ṣẹlẹ laipẹ yii ni ti adajọ agba orilẹ-ede Naijiria Walter Onnoghen ti igbimọ CCB gbe lọ siwaju ile ẹjọ to n gbọ ẹsun aṣemaṣe awọn to dipo ilu mu lorilẹ-ede Naijiria, CCT lori ẹsun pe o kọ lati kede dukia rẹ.

Àkọlé fídíò, Eko Akete yóò gbàlejò BBC Yoruba

Bayii, ijọba apapọ ti ni ki wọn ṣi fi silẹ naa ati pé ọpọlọpọ amofin lo gbà pé kò tọna lati

Walter Onnoghen

Oríṣun àwòrán, NBA

Àkọlé àwòrán, Ẹsun lori dukia awọn to dipo ilu mu

Ẹlomiran to tun jẹjọ lori iru ẹsun bayii ni Abẹnugan ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja Bukola Saraki. Ẹ sun ti wọn fi kan Saraki ni pe irọ lo pa pẹlu dukia rẹ to kede.

Awọn agbẹjọro to le lọgọrun ti ẹ ṣoju Saraki lẹẹkan ṣoṣo nile ẹjọ nibi ti wọn ti n ṣe igbẹjọ ọhun.

Àkọlé fídíò, Oduduwa Alphabet: òmìnira èdè ti dé fún Port Novo báyìí

Awọn wọnyi ti wọn dipo ilu mu ni wọn ti wọn si ti foju ile ẹjọ lori ẹsun pe wọn kọ lati kede

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, Fcaebook/Abubakar Bukola Saraki

Àkọlé àwòrán, Ijẹjọ lori ikede dukia

Oloṣelu nla miran to tun jẹjọ niwaju CCT ni gomina Ipinlẹ Eko tẹlẹ ri, Bola Ahmed Tinubu. Wọn fẹsun kan Tinubu pé o pa irọ nigba to kede dukia rẹ nigba naa.

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter/APC

Àkọlé àwòrán, Bola Tinubu jẹjọ ni waju CCT

Ọga ile iṣẹ ifọpo rọbi Naijiria, NNPC ni wọn tun fẹsun kàn sẹyin pé ko ṣalaye.

oga NNPC

Oríṣun àwòrán, NNPC

Àkọlé àwòrán, Ile ẹjọ CCT nii ṣe pẹlu àwọn oloṣelu ati dukia wọn
Àkọlé fídíò, Sibahle Zwanen fi ìmọ̀ ìṣìro da orí ayélujára rú