EPL: Guardiola ní k'áwọn agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ gbàgbé nípa Liverpool

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu manchester City Pep Guardiola gboṣuba kare fawọn agbabọọlu ikọ naa lẹyin ti wọn fagba han Wolves pẹlu ami ayo mẹta sodo lọjọ Aje ninu idije Premier League.
Ẹlẹsẹ ayo Gabriel Jesus lo kọkọ gbayo meji sawọn ki Conor Coady to ṣaṣiṣe gba ẹlẹẹkẹta wọle ikọ Wolves.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ikọ Manchester City si lo wa ni ipo keji ninu idije Premier League pẹlu ami mẹtalelaadọta nigba ti Liverpool wa loke pẹlu ami mẹtadinlọgọta.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bo tilẹ jẹ pe awọn mẹwaa ninu awọn agbabọọlu Wolves lo pari ifẹsẹwọnsẹ ọhun lẹyin ti rẹfiri le ọkan lara jade nigba to gbe Bernardo Silva ṣubu lọna to lewu, Guardiola eyi ko mu ki ere bọọlu naa rọrun.
Ẹwẹ, akọnimọọgba Guardiola rọ awọn agbabọọlu rẹ tẹsiwaju pẹlu igbiyanju wọn ki wọn si gbagbe nipa Liverpool to wa loke tente.
Guardiola ni ki awọn agbabọọlu Man City kọ eti ikun si ọrọ ti awọn kan sọ pe awọn ifẹsẹwọnsẹ to wa ni waju Liverpool ko le lati bori fun wọn.
Man City yoo koju Huddersfield Town ninu ifẹsẹwọnsẹ to kan fun wọn ninu idije Premier League.










