Afcon2019: Egypt ni yóò gbàlejò Afcon 2019

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n mojuto ere bọọlu nilẹ Afrika ti kede orileede Egypt gẹgẹ bi orileede ti yoo gbalejo idije Afcon 2019.
Wọn sun ikede naa wa si waju lati ọjọru si ọjọ iṣẹgun.
Ajọ CAF ko fi alaye kankan sita lori isunsiwaju yii.
Lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa ni wọn kede Egypt saaju orileede South Africa gẹgẹ bi orileede ti yoo gbalejo idije Afcon 2019.
Orilẹede Egypt ati South Africa ni wọn jọ n du ati gba alejo idije naa.
Orileede Cameroon to yẹ́ ko gbalejo rẹẹ̀ padanu anfaani naa latari ipalẹmọ wọn ti ko munadoko to.
Amọ ṣa, CAF ti fun wọn ni anfaani miiran lati tun ọmọluabi wọn ṣe pẹlu gbigba alejo idije lọdun meji si isinsinyi.
Itunmọ eleyi si ni wi pe awọn to yẹ ki wọn gba alejo idije naa ni ọdun 2021 ati 2023 yoo sinmi na.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orileede Ivory Coast to yẹ ki wọn gbalejo idije 2021 ko faramọ igbesẹ yi ti wọn si ti gbe ọrọ naa lọ si iwaju ile ẹjọ to n pẹtu saawọ to niṣe pẹlu ere idaraya.
Ẹni to ba jawe olubori lati gba alejo idije yiI lọdun 2019 yoo mura gidi ni nitori oṣu mẹfa pere ni wọn yoo ni lati palẹmọ fun idije naa ti orileede merinlelogun fẹ kopa ninu rẹ laarin ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹfa Si ọjọ kẹtala oṣu keje.
Ikede ẹni ti yoo gbalejo idije naa yoo waye lolu ilu Senegal ti ṣe Dakar.
Ayẹyẹ ami ẹyẹ Caf ọlọdọọdun yoo tẹle ikede naa lonIi.
Mohammaed Salah orileede Egypt n lero lati gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede fun igba ẹkẹta.
Pierre-Emerick Aubameyang Gabon ati Sadio Mane Senegal ni wọn n ba du ipo naa.













