AFCON: Cameroun kò ní leè gbàlejò ìdíje nítorí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan

Ikọ agbabọọlu Cameroun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àjọ CAF ní àyè wà fún Cameroun láti gbàlejò ìdíje AFCON láìpẹ́ bí ó bá tètè tún ilé rẹ̀ tò

Orilẹede Cameroun ko ni lee gbalejo idije ife ẹyẹ agbabọọlu orilẹede Afirika, AFCON ti yoo waye ni ọdun 2019 mọ.

Ajọ ere bọọlu ni ilẹ Afirika, CAF lo sọ eyi di mimọ lẹyin ipade kan eyi to ṣe ni ilu Accra lorilẹede Ghana ni ọjọ ẹti.

Ajọ naa ni lẹyin oniruuru abẹwo fun bi oṣu mejidinlogun, awọn alaṣẹ orilẹede naa ko tii mu awọn amuyẹ to yẹ fun gbigbalejo idije naa ṣẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọrọ abo ni o ga ju ninu awọn igbelewọn eleyii to ja orilẹede Cameroun kulẹ.

Ogun ẹya si ẹya to n waye lawọn apa kan orilẹede naa ko lee ṣai jẹ ọkan gboogi ninu ọrọ abo to ja igbalejo idije AFCON gba mọ Cameroun lọwọ.

Nibayii, orilẹede Morocco tabi South Africa ni ireti wa pe o ṣeeṣe ko ja mọ lọwọ.

Amọ awọn alaṣẹ ajọ CAF ti jẹ ko di mimọ pe ikede orilẹede tuntun ti yoo gbalejo idije naa yoo waye titi ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 2018.