Akọsilẹ nipa awọn oludije fun ipo aarẹ ni 2019

Eyi ni bi o ṣe ni anfaani si diẹ lara awọn oludoje
  • Ẹgbẹ oṣelu
    People's Democratic Party (PDP)
    Ọjọ ibi
    25 oṣu Kọkanla 1946, Jadam ipinlẹ Adamawa
    Akọsilẹ nipa wọn
    • Oniṣowo ati oloṣelu
    • Igbakeji Aarẹ Naijiria laarin 1999 si 2007
    • O dupo aarẹ ni 2007 labẹ ẹgbẹ oṣelu Action Congress (AC), ṣugbọn o kuna.
    • Wọn dibo yan an si ipo gomina ipinlẹ Adamwa ni 1998. Ṣugbọn wọn ko ti i bura fun ti ẹgbẹ osẹlu People's Democratic Party (PDP) lati ṣe igbakeji Oluṣẹgun Ọbasanjọ to fẹ dupo aarẹ. Awọn mejeeji jawe olubori ninu eto idibo to waye loṣu Keji 1999, wọn si bura fun Abubakar lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun 1999, gẹgẹ bi igbakeji aarẹ Naijiria keji ti wọn dibo yan ninu oṣelu awaarawa.
    • O dupo gomina ni ipinlẹ Gongola (to ti di Adamawa ati Taraba bayii) lọdun 1991, o si fidirẹmi.
    • O dupo aarẹ ni 1993, o si ṣe ipo kẹta ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party.
    • O ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ aṣọbode Naijiria fun ọdun mẹẹdọgbọn, 1964 si 1989.
  • Ẹgbẹ oṣelu
    Alliance for New Nigeria (ANN)
    Ọjọ ibi
    Ọjọ kejila oṣu Karun, Ibadan, ipinlẹ Ọyọ
    Akọsilẹ nipa wọn
    • Onimọ nipa okoowo ati sọrọsọrọ agbani nimọran
    • O maa n ṣe idanilẹkọ fun awọn olokoowo ni ilẹ Afrika lori bi a ṣe n jẹ adari ni Fasiti Stamford/Seed Program.
    • Oun ni Ọga Agba leadership development institution, Gemstone Group.
  • Ẹgbẹ oṣelu
    Young Progressive Party (YPP)
    Ọjọ ibi
    Ọjọ keje oṣu Karun 1963 ni ipinlẹ Eko
    Akọsilẹ nipa wọn
    • Agbẹjọro ati onimọ ọrọ aje
    • Igbakeji Gomina banki apapọ Naijiria ni 2009 si 2014. O si tun jẹ ọmọ igbimọ Monetary Policy.
    • Moghalu jẹ oṣiṣẹ to wa fun ọrọ oṣelu ni ẹka Department of Peacekeeping Operations ni olu ileeṣẹ ajọ UN to wa ni New York lọdun 1996 si 1997.
    • O jẹ oludamọran nipa ofin fun United Nations International Criminal Tribunal fun Rwanda ni 1997, wọn si pada gbega si ipo agbẹnusọ dun ile ẹjọ naa.
    • Wọn yan sipo Olori ikọ to wa fun ajọsẹpọ ati ṣiṣe amulo dukia ninu ajọ World Health Organisation.
  • Ẹgbẹ oṣelu
    All Progressives Congress (APC)
    Ọjọ ibi
    Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, 1942, Daura, ipinlẹ Katsina
    Akọsilẹ nipa wọn
    • Aarẹ lati 2015 di asiko yii.
    • Alaga ajọ Petroleum Trust Fund, 1994
    • Aarẹ ologun nigba kan, 31 oṣu Kejila 1983 si 27 osu Kẹjọ 1985
    • O dupo aarẹ lọdun 2003 ati 2007 labẹ ẹgbẹ oṣelu All Nigeria People's Party (ANPP), ṣugbọn Aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party fi ẹyin rẹ janlẹ.
    • O tun pada dije ni 2011 labẹ ẹgbẹ oṣelu Congress for Progressive Change (CPC), ṣugbọn Aarẹ Goodluck Jonathan to wa lori oye nigba naa lo jawe olubori.
    • Kọmisana ijọba apapọ fun epo bẹtiro ati awọn nkan alumọọni lọdun 1976 si 1979.
    • Gomina ipinlẹ Borno laarin oṣu Keji si oṣu Kẹta 1976.
    • O tun jẹ gomina fun ipinlẹ Ila oorun ariwa ni 1975 si 1976
  • Ẹgbẹ oṣelu
    African Democratic Congress (ADC)
    Ọjọ ibi
    Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila 1956, ni Randa, Sanga, ipinlẹ Kaduna.
    Akọsilẹ nipa wọn
    • Onimọ nipa ọrọ aje, oṣiṣẹ banki, ati onimọ nipa idagbasoke agbaye
    • Igbakeji Gomina Banki apapọ Naijiria ni 2005 si 2007.
    • O jẹ oludamọran pataki fun Aarẹ Jonathan lori eto ọrọ aje ati eto ijọba, ọmọ igbimọ Economic Management Team, ati oṣiṣẹ African Development Bank Group.
  • Ẹgbẹ oṣelu
    Allied Congress Party of Nigeria (ACPN)
    Ọjọ ibi
    Wọn bi ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹrin 1963 ni ipinlẹ Anambra
    Akọsilẹ nipa wọn
    • Oluṣiro owo Agba ati onimọ eto ọrọ aje
    • Aarẹ ẹka Banki Agbaye ni Afrika lọdun 2007 si 2012.
    • Minisita fun awọn nkan alumọni lọdun 2005 si 2006.
    • Minisita fun eto ẹkọ lọdun 2006 si 2007
    • Wọn fi orukọ rẹ silẹ fun ami ẹyẹ Nobel Peace Prize
    • Ọkan lara awọn Oludasilẹ ẹgbẹ Bring Back Our Girls ati Transparency International
  • Ẹgbẹ oṣelu
    African Action Congress (AAC)
    Ọjọ ibi
    Wọn bi ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu Keji, 1971, ni Kiribo, ipinlẹ Ondo.
    Akọsilẹ nipa wọn
    • Oniroyin, ajafẹtọ ati ontẹwe.
    • O da ileeṣẹ iroyin ori ayelujara Sahara Reporters silẹ ni 2006 pẹlu afojusun lati gbe aṣa ilẹ Afrika larugẹ. Ati lati tu aṣiri iwa ibajẹ ninu iṣejọba.
    • Olori awọn akẹkọọ ni Fasiti ilu Eko.

Ọna ti a gba ṣe akojọ

Awọn ọna ti a gba ṣe akojọ awọn oludije sipo aarẹ da lori:
  • Awọn ẹgbẹ to wa nile asọfin
  • Awọn ẹgbẹ oṣelu to gbajumọ (ti ko ni oludije to gbajumọ)
  • Awọn oludije to gbajumọ ninu ẹgbẹ oṣelu ti ko gbajumọ
  • Bi wọn ṣe gbajumọ ninu iroyin to n jade
  • Bi wọn ṣe n ṣe si loju opo ibaraẹnidọrẹ (Social Media)

Orisun Aworan

Getty, www.fela2019.com, atiku.org, tobuildanation.com, facebook, sowore2019.org

Awọn to ṣe akojọpọ yii

Oludasilẹ: Ọlawale Malọmọ. Oluwadi: Nkechi Ogbonna