Yollywood: Àwọn òṣèré Yorùbá t'Élédùwà gbà fún àmọ́ tí wọn kìí ṣe ọmọ ilẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, Instagram
Yoruba bọ, wọn ibi ti ori ba da ni si laa gbe. Bi ọrọ ti ri ree fawọn gbajugbaja oṣere ori itage Yoruba ṣugbọn ti wọn kii ṣe ọmọbibi ilẹ kaarọ oo jiire.
Ede Yoruba wọn dan mọran, koda wọn maa n pa owe ninu ere nibi ti ede Yoruba ye wọn de.
Lootọọ ni wọn wa lati awọn ipinlẹ mii lapa Gusu orilẹede Naijiria, amọ ere ori itage Yoruba lori fi ran wọn.
- Wo ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ táwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run sọ nípa ọdún 2021
- Dangote já mi kulẹ̀ lóri ọ̀rọ̀ ìfẹ́ àmọ́ ó kọ́ mi bá a ṣé lówó - Ọ̀rẹ́bìnrin Dangote lahùn
- Gbogbo ọjọ́ kérésì ni ìyá Leah Sharibu ń sàìsàn, ó tún ti wà nílé ìwòsàn
- Gbàjarè! Ràkúnmí làwọn agbébọn ń lò láti gbé àdó ikú wọ òkè ọya - Arewa figbe ta
- Bí 2020 ṣe ń lọ sópin, Alapinni Oosa wúre ọdún fún ọmọ Yorùbá
- A ti yí orin ọdún ń lọ sópin sí èdè Igbo àti Hausa - Mama Fasoyin
Wọnyii lawọn gbajugbaja oṣere ori itage Yoruba ti wọn kii ṣe ọmọ ilẹ Yoruba.
Mercy Aigbe (Ipinlẹ Edo)

Oríṣun àwòrán, Instagram/realmercyaigbe
Wọn bi oṣere Mercy Aigbe lọjọ kinni oṣu kinni ọdun 1978 ni ipinlẹ Edo.
Yatọ si ere ṣiṣe, Aigbe tun maa n dari ere, bakan naa lo tun jẹ oniṣowo.
Ilumọọka ni Mercy jẹ lagbo ere tiata Yoruba, odu ni kii ṣe aimọ fun oloko.
Ilu Benin tii ṣe olu ilu ipinlẹ Edo lo ti wa.
Kelvin Ikeduba (Ipinlẹ Delta)

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kelvin Ikeduba
Odu ni Ọgbẹni Kelvin Ngozi Ikeduba lagbo oṣere tiata Yoruba, ki ṣe aimọ fun oloko.
Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹjọ ọdun 1976 ni wọn bi Ikeduba.
Oriṣiiriṣii ipa ni Ikeduba maa n ko ninu ere, eyi to si ti mu un gba oniruuru ami ẹyẹ nibi ere ṣiṣe.
Bi Ikeduba ṣe maa n ṣere Yoruba naa lo maa n kopa ninu ere oloyinbo.
Lootọọ ni Ikeduba jẹ ọmọ ipinlẹ Delta, ṣugbọn agbegbe Ebute-Meta niluu Eko ni wọn bi i si.
Fathia Balogun (Ipinlẹ Delta)

Oríṣun àwòrán, Facebook/Fathia Williams
Ta ni ko mọ gbajugbaja oṣere Fathia Balogun lagbo ere ori itage Yoruba ayafi ẹni to ba fẹ ṣe eke.
Ọmọ ipinlẹ Delta ni Fathia i ṣe.
Ọjọ karun oṣu keji ọdun 2021 yii ni Fathia yoo pe ọdun mejilelaadọta loke eepẹ.
Ilu Ikeja ni wọn bi Fathia si nipinlẹ Eko lọjọ karun un oṣu keji ọdun 1969.
Toyin Abraham (Ipinlẹ Edo)

Oríṣun àwòrán, Instagram/Toyin Abraham
Tọmọde tagba lo mọ Toyin Abraham ninu ere itage Yoruba ṣiṣe.
Toyin gbaju gbaja lagbo oṣere Yoruba kii ṣe diẹ, koda o ti ṣe oriṣiiriṣii fiimu Yoruba.
Amọ ọmọbibi ilu Auchi ni ipinlẹ Edo ni Toyin.
Toyin maa n dari ere, koda o tun maa n ṣe olootu rere yatọ si ere ṣiṣe ti ọpọ mọ ọn si gan an.
Ọjọ karun un oṣu kẹsan an ọdun 1982 ni wọn bi Toyin, o si gbe ilu Ibadan dagba.
Oṣere tiata ẹgbe rẹ, Adeniyi Johnson ni Toyin kọkọ fẹ, amọ igbeyawo ọhun fori ṣanpọn ki o to fẹ Kola Ajeyemi ti wọn jọ wa papọ bayii.
Regina Chukwu(Ipinle Enugu)

Oríṣun àwòrán, Instagram/Regina Chukwu
Regina Chinedu Chuwku ti ọpọ mọ si Regina Chukwu jẹ ọmọ ipinlẹ Enugu amọ ilu Eko lo ti dagba.
Ọjọ kẹtalelọgbọn oṣu kẹta ọdun 1980 ni wọn bi Regina.
Ilu Eko lo ti lọ ile iwe girama ki o to tẹsiwaju lọ si ile iwe gbogbonṣe Lagos State Polytechnic.
Regina ti kopa ninu oriṣiiriṣii ere bii Akun", "Awolu ati Awalu", "Ewatomi", "Idaro", "Ogunso" atawọn ere Yoruba mii.
Regina ṣe igbeyawo amọ o padanu ọkọ rẹ lẹyin ọdun mẹrin ti wọn ṣe igbeyawo.
Ṣugbọn Eleduwa fi ọmọ meji, ọkunrin kan ati obinrin kan ta idile rẹ lọrẹ ki ọkọ rẹ to papoda.












