Àwọn wòòlí ń takora lórí ẹni tí yóò di ààrẹ láàrin Buhari àti Atiku

Olùdásílẹ̀ ìjọ One Love Family, Satguru Maharaj ní ààrẹ Muhammadu Buhari tó ń dije lábẹ àsía ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Party (APC), ni yóò fidi alátako rẹ̀ Alhaji Atiku Abubakar, tó ń dije lábẹ́ égbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party(PDP) janlẹ̀. níbi idibo gbogboogbo ti yóò wáyé lósù tó ń bọ.
Asọtẹlẹ yii waye lẹyin Osun meji ti adari ijọ Divine Seed of God ti ilu Ibadan Wooli Wale Olagunju sọ asọtẹlẹ wipe, ki Buhari ma ṣe wahala pupọ o, nitori wipe Atiku ni yoo gbe igba oroke.
O ba awọn oniroyin sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan nibi to ti sọ wipe, oun n ki Atiku ku ori ire, nitori wipe, yoo bori ninu idibo 2019.

Oríṣun àwòrán, Wale Olagunju
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Buhari, Atiku, Ezekwesili, Sowore àti àwọn méjìléláàdọ́rin míràqn ló ń dije dupò ààrẹ Nàìjíríà.

Oríṣun àwòrán, Bayo Omoboriowo
Lásìkò tí Gúrú ń bá àwọn àkọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nibi àpérò láti se ayẹyẹ ọdún mọ́kàndínlógojí rẹ̀ lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà, ló ti sàlàyé pé òun rí pe Buhari ló jáwé olúbori nínu ìdíje ìdìbò ọdún 2019.
Ó nií ti àwọn olùdíje tó kù yóò ba gbọ́ ti toun kí gbogbo wọn gbárùkù tí Buhari ní yóò ṣe wọn láǹfàní.









