Sunday Igboho: Igboho láṣẹ lábẹ́ òfin Nàìjíríà láti bọ ohun tó wù ú nígbà tó wù ú- Yinka Oyebode

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ijọba ipinlẹ Ekiti ti ni awọn gbọ wi pe eekan ọm Yoruba, Sunday Igboho lọ si igbo Ire-Ekiti lati lọ bọ Ogun.
''Lọ́ọ̀tọ́ ní Sunday Igboho wá sí igbó Ire-Ekiti láti bọ Ogun lákáyé! ''
Akọwe eto iroyin fun gomina ipinlẹ Ekiti, Yinka Oyebode lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba lẹyin fidio to jade lori ayelujara,to safihan Sunday Igboho ninu igbo Ire-Ekiti.
Arakunrin Oyebode ni Igboho laṣẹ ni abẹ ofin lati lọ si ibikibi to ba wu u nitori ọmọ orilẹede Naijiria ni, to si le e ṣe ẹsin to ba wu u.
Akọwe Ekiti ni: 'Amọ agbegbe Ire-Ekiti fun ibi ti awọn eniyan gbagbọ nipa bibọ Ogun, nitori naa a gbọ wi pe oun nbọ nibẹ''
''Oun ti o lọ ṣe nipe o lọ darapọ mọ awọn ẹlẹsin ibilẹ lati lọ bọ Ogun gẹgẹ bi igbagbọ rẹ''
Saaju ni fidio kan ti ja ranyin lori ayelujara nibi ti awọn eniyan ti tu yaya sita lati ki Sunday Igboho kaabọ ni agbegbe wọn.
Lẹyin naa ni wọn lọ si ojubọ Ogun lati lọ ṣe adura ati iṣẹṣe.

Awọn ero lo pejọ naa wa ni ibi ojubọ Ogun naa lati oru titi di owurọ lati rubọ ati lati ṣe adura.
- Ọjà oùnjẹ ti ń wọ ilẹ̀ Yorùbá àti Igbo láti ilẹ̀ Hausa báyìí- Alhaji Aminu
- "Sọ́jà fi ìbọn gé mi lọ́wọ́ kó lè fipá bámi lòpọ̀"
- Wòlíì Kasali gba Bunmi ìyàwó rẹ̀ àkọ́fẹ́ padà, ìjà parí!
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó ń ṣe ayédèrú abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19
- Buhari ni káwọn agbófinró ó yìnbọn fáwọn tó ń gbé ìbọn AK-47, àwọn ọmọ Nàìjíríà n pariwo "lórí irọ́"
Awọn eniyan ti wọn n sọrọ ninu fidio naa sọ wi pe awọn ara agbegbe Ire-Ekiti gba ni alejo wa si agbegbe wọn.
Ti wọn si fun un ni ọpa aṣẹ ti Ogun lo nigba aye rẹ lati fi jagun.
Awọn ẹlẹsin ibilẹ gbagbọ wi pe ilu Ire-Ekiti ni Ogun wọlẹ si, ti wọn si ma n lọ si ojubọ rẹ lati bọ ọ ni orekoore.
Bakan naa ni wọn n yin ibọn kalukalu lati fi bọ Ogun gẹgẹ bi iṣe wọn lasiko ti wọn ba n bọ orisa naa.
- Àwọn ará abúlé kan ṣàwàrì àlùmọ́ọ́nì gòólù ní wọ́n bá kígbe síta ní Ọlọ̀pàá bá yi wọn ká!
- Wo ibi tí o ti lè fi orúkọ síìmù rẹ sílẹ̀ tàbí gba nọ́mbà tuntun tí síìmù rẹ bá sọnù
- Báwo ní Ọba Rilwan Akiolu tí ìlú Eko ṣe ní $2 million àti N17 million sí inú àfin rẹ̀?
- Lọ́ọ̀tọ́ ní Sunday Igboho wá sí igbó Ire-Ekiti láti bọ Ogun lákáyé!- Akọ̀wé ìpínlẹ̀ Ekiti
- Àwọn Agbébọn ti dáná sún agbègbè Maru nípinlẹ̀ Zamfara, wọ́n tún jí èèyàn tó lé lọ́gọ́ta gbé lọ
Nǹkan dé, Igboho ní káwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá lọ múra ògùn jọ nítorí ohun tó ń bọ̀ lọ́nà
Eekan ọmọ Yoruba ni, Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti ṣeleri ati da sẹria to ba yẹ fun awọn oloṣelu ọmọ ilẹ Yoruba to ba gbiyanju ati darapọ mọ idije ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Others
Igboho to sọ eleyii nigba to n ba ọpọ ero kan sọrọ̀ nibi eto kan laipẹ yii.
O ṣalaye pe, dipo ki awọn oloṣelu ẹya Yoruba o maa gbaruku ti ipe fun ijijangbara ilẹ Yoruba, ipolongo lati dije fun ipo aarẹ ni wọn n le kaakiri."
O ni oun o ni gba kawọn oloṣelu ilẹ Yoruba kan laaye lati dije nitori oun ṣetan lati gbẹmi wọn ki idibo naa gan to waye.
Bakan naa lo tun rọ awọn agbagba ilẹ Yoruba lati dide fun ijijagbara ilẹ Yoruba.
Ninu ọrọ rẹ, o ni imọtara-ẹni-nikan lo n ba awọn oloṣelu ilẹ Yoruba ja ti wọn fi n polongo fun ilepa ara wọn lati di aarẹ.
O ni oun yoo ba wọn ja bi wọn ba gbero rẹ.
Bakan naa ni Igboho tun ke sawọn ọdọ lati lọ ṣe oogun abẹnugọngọ lati lee fi gbeja ara wọn lasiko ipenija to n bọ lọna.
- Àwọn ajínigbé fìyà jẹ́ wa lọ́nà igbó tí wọ́n kó wa lọ- Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin GSS Zamfara
- Ẹ wo èrò àwọn ènìyàn lórí bí Gòmìná Akeredolu ṣe fòfin de NURTW, RTEAN nípínlẹ̀ Ondo
- Owó Taxi ní ìpínlẹ̀ Ondo tí padà sí N50 látí N100 nítorí kò sí gbígba ''tíkẹ́ẹ̀tì'' NURTW mọ́
- Ọ̀jọ̀gbọ́n Ijeoma ní òun kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà mọ́, South Africa tó yàn dípò bá tún lé e jáde
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára, Covid 19 ti balẹ̀ bàgẹ̀ sí orílẹ̀èdè Naijiria
















