LASTMA, Alleged impersonation: Àjọ LASTMA ní ó ṣòro púpọ̀ láti mọ ayédèrú òṣìṣẹ́ àjọ náà l'Eko

Oṣiṣẹ LASTMA

Oríṣun àwòrán, Facebook/LASTMA

O nira gan an lati mọ awọn oṣiṣẹ ajọ LASTMA to jẹ ayederu yatọ si awọn t jẹ ojulowo.

Agbẹnusọ fun ajọ LASTMA nipinlẹ Eko, Olumide Filade lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba.

Ọgbẹni Filade sọ pe awọn ayederu oṣiṣẹ LASTMA maa n ṣi kiri lati agbegbe kan si omiran lo jẹ ko nira lati mu wọn Ọwọ́ pálábá ayédèrú òṣìṣẹ́ LASTMA ségi ní Mushin ní ìpínlẹ̀ Eko.

Ogbeni Falade ni: ayederu oṣiṣẹ LASTMA, Shakiru Agbaje ti ọwọ palaba rẹ segi di minu nitori awọn eeyan adugbo Mushin to ta ajọ naa lolobo.

O ni iṣẹ iwadii lo ṣe iranwọ ti ajọ LASTMA fi ri Ọgbẹni Agbaje mu.

Àkọlé fídíò, Bone setting: Adimula Kehinde Akinfenwa ṣàlàyé nípa irúfẹ́ ẹranko tí wọ́n fi ń to eegun èy

Agbẹnusọ LASTMA sọ pe iwadii si n lọ lọwọ lori Agbaje ti wọn mọ.

Ọgbẹni Filade ṣalaye pe ọrọ naa ti dọdọ awọn ọlọpaa bayii nirori o niṣe pẹlu iwa ọdaran.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award'ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀

Ogbeni Falade ni: ''LASTMA gba aṣọ lọwọ Agbaje lẹyin ti wọn da a duro lẹnu iṣẹ, ṣugbọn ọpọ iru wọn maa n ran aṣọ mii lati huwa ọdaran ni,'' agbẹnusọ LASTMA lo sọ bẹẹ.

O ni bawọn ti wọn ba ti da duro lẹnu iṣẹ ọlọpaa ati ologun ṣe maa n ran aṣọ lati maa lu awọn eeyan ni jibiti lawọn ti LASTMA naa ba duro maa n ṣe.

Ọwọ́ pálábá ayédèrú òṣìṣẹ́ LASTMA ségi ní Mushin ní ìpínlẹ̀ Eko

Ọwọ palaba ayederu oṣiṣẹ ẹṣọ oju popo LASTMA kan, Shakiru Agbaje, niluu Eko segi lẹyin ti ajọ naa fi ọwọ ofin mu un.

Ni agbegbe Mushin ni wọn ti gba Ọgbẹni Agbaje to ti figba kan ṣiṣẹ pẹlu ajọ LASTMA ṣugbọn ti wọn ti da duro lẹnu iṣẹ lati ọdun mẹsan an sẹyin mu.

Awọn oṣiṣẹ LASTMA

Oríṣun àwòrán, Facebook/LASTMA

Nigba to n ṣalaye bi ajọ LASTMA ṣe gba ọkunrin naa mu, ọga agba LASTMA nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Olajide Oduyoye sọ pe ajọ LASTMA da ọkunrin ọhun duro lẹnu iṣẹ lori o lo ayederu iwe ẹri ati pe o tun lu jibiti.

Oduyoye ni o ti pẹ ti Ọgbẹni Agbaje ti n dunkoko mawọn awakọ lagbegbe Mushin ti o si n huwa ọdaran nibi ti o ti n pe ara rẹ ni oṣiṣẹ LASTMA.

Ọga agba LASTMA ni oriṣiiriṣii iwa ọdaran ti Agbaje hu sawọn awakọ lagbegbe Mushin ti ba orukọ ajọ naa jẹ.

Àkọlé fídíò, LASTMA Yesufa: Àwọn dókítà gbìyànjú lórí ojú mi ṣùgbọ́n...

O ni gbogbo awọn ti LASTMA ti da duro lẹnu iṣẹ ṣugbọn ti wọn si tun n wọ aṣọ LASTMA kiri lati huwa bajẹ lọwọ yoo tẹ.

Ọga agba LASTMA rọ awọn araalu lati maa wo orukọ awọn oṣiṣẹ LASTMA to ba dawọn duro tabi ni itakurọsọ pẹlu wọn.

Ọgbẹni Oduyoye rọ awọn awakọ lati pa gbogbo ofin irinna ipinlẹ mọ ti wọn ba n wakọ loju popo.

Ọga agba LASTMA naa sọ pe ajọ naa yoo fi to araalu leti iru ijiya to tọ si Agbaje lẹyin ti iṣẹ iwadii ba pari lori ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rs Sunday Igboho, ṣùgbọ́n..- Oba Olugbọn