Liverpool vs Chelsea: Ayé àkámarà! Liverpool laná ní Anfield, Chelsea pa òkúta sí gaàrí wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ogun laye, ọmọ araye le! Ijamba mii tun ṣe ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool lalẹ Ọjọbọ lẹyin ti Chelsea lu wọn mọle.
Eyi ni igba ifẹsẹwọnsẹ karun un ti Liverpool yoo fidi rẹmi ninu rẹ ni papa iṣere wọn ni Anfield.
Kete ti wọn bẹrẹ ere bọọlu naa ni Chelsea ti bẹrẹ si ni gbiyanju lati gba bọọlu sawọn Liverpool nigba ti Liverpool ko si le ta putu.
- Áwa Hausa tá a wà l'Ogbomoṣọ ti di Yorùbá- Oba Haruna Sabo Ogbomoso
- Ilé ẹjọ́ sọ àwọn afurasí méje sí àtìmọ́lé lóríi rògbòdìyàn tó wáyé ní ọjà Ṣaṣa
- Ọjà oùnjẹ ti ń wọ ilẹ̀ Yorùbá àti Igbo láti ilẹ̀ Hausa báyìí- Alhaji Aminu
- Wòlíì Kasali gba Bunmi ìyàwó rẹ̀ àkọ́fẹ́ padà, ìjà parí!
- Wòlíì Kasali gba Bunmi ìyàwó rẹ̀ àkọ́fẹ́ padà, ìjà parí!
Ẹlẹsẹ ayo, Timo Werner lo kọkọ gba goolu sawọn Liverpool nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun de iṣẹju mẹrinlelogun.
Amọ, ẹrọ oloju aṣa VAR wọgile goolu naa pe o ti wọ ''off side'' ko to gba bọọlu sawọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣugbọn agbabọọlu aarin gbungbun, Mason Mount gba goolu miran wọle nigba ti ipele akọkọ ku iṣẹju mẹta ko pari.
Liverpool gbiyanju titi lati da ayo naa pada ṣugbọn omi pọ ju ọka lọ fun wọn.
Ni bayii, ipo keje ni ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool wa lori tabili idije Premier League.
Chelsea ti wa ni ipo kẹrin lẹyin ti wọn ko fidi rẹmi ninu ere bọọlu mẹwaa ti wọn ti gba lati igba ti Thomas Tuchel ti di akọnimọọgba wọn.
Ẹwẹ, agbabọọlu Liverpool tẹlẹ ri, Jamie Carragher ti rọ ẹgbẹ agbabọọlu naa lati ra awọn agbabọọlu tuntun to dantọ.
Carragher ni Liverpool nilo awọn agbabọọlu tuntun lati sọji pada.












