Àlàyé rèé bí òṣìṣẹ́ LASTMA ṣé kàn àgbákò ikú lọ̀wọ̀ àwọn jàńdùkú méjì nílu Èkó

Oríṣun àwòrán, Lastma
Ọga agba ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ nilu Eko ,LASTMA, ti bẹnu atẹ lu bi awọn eeyan ti ṣe n dunkoko mọ awọn oṣiṣẹ ajọ naa.
Ọgbẹni Olajide Oduoye sọ ọrọ yi lyin ti ọkan ninu awọn oṣiṣẹ rẹ di ero ọrun latari ikọlu tawọn janduku kan ṣe si nilu Eko.
Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ ninu atẹjade kan ti Filade Olumide to jẹ igbakeji alukoro ajọ naa fi sita,ni nkan bi ago marun un irọlẹ lawọn janduku naa ju ọkuta nla kan lu Ola Oyesina nibi to tin dari lilọ bibọ ọkọ ni agbegbe Iganmu -Sifax ni Apapa.
''Wọn ṣare gbe Oyeshina ati awọn to ju oko lu u lọ lọ si agọ ọlọpaa Area B.Ọga ọlọpaa Bayo Suleiman ni ki wọnfi awọn janduku naa si ahamọ ti wọn si sare gbe Oyeshina lọ si ile iwosan LUTH.''
''O ṣeni laanu pe arakunrin yi jẹ ọlọrun nipe lowurọ ọjọ Abameta tii ṣe ọgbọn ọjọ Oṣu Kọkanla''
Ọga Lastma naa wa ṣeleri pe awọn to da ẹmi arakunrin naa legbodo yoo foju ba ile ẹjọ.
O ni eleyi yoo jẹ ọna kan gbogi lati jẹ ki awọn to ba n gbero lati kọlu awọn oṣiṣẹ awọn tọwọ ọmọ bọ aṣọ''
Ofi kun ọrọ rẹ pe pẹlu ifilọlẹ igbimọ apapọ awọn oṣiṣẹ aabo lati dẹkun iwa ibajẹ nilu Eko,ko ni si ibi tawọn aṣebi yoo sapamọ si mọ












