Sunday Igboho ò lẹ́bi, ìjọba ló làbùkù lórí wàhálà Fulani darandaran- Oba Olugbọn
Ìjọba ló ni àbùkù àìbìkítà lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho- Oba Olugbọn ti Orile-Igbọn
Emi ko sọ pe ki eeyan maa da ofin ṣe ṣugbọn ko si igba ti onikaluku ko ni dide fun eto aabo ara rẹ- Olugbọn
Se ẹ ranti Oba alade ilẹ Yoruba to pari ede aiyede to ṣẹlẹ larin Sunday Ighoho ati Ooni ti Ile Ife laipẹ?
BBC Yoruba ti ṣabewo si aafin Olugbọn ti Orile Igbon ni Ogbomoso ni ipinlẹ Oyo ni guusu iwọ oorun Naijiria.
Oba Francis Olusola-Alao to je igbakeji alaga awọn lọbalọba ni ipinlẹ Oyo ba BBC Yoruba sọrọ ilẹ kun.
Kabiesi sọrọ pupọ lori ọrọ ajijangbara iran Yoruba ni, Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ n pe ni Sunday Igboho.

Oríṣun àwòrán, others
Oba Francis ni ijọba Naijiria ti kuna ni ojuṣe wọn lati daabo bo awọn eeyan ti wọn n dari lasiko yi.
O ni: Bẹẹ, ti ẹnikan ba n ro pe ohun ti Sunday Igboho n ṣe ko dara to, ki lo de ti ẹyin naa ko kuku lọ ṣe bi akọni.
Oba Francis Olusola-Alao salaye pe ofin ijọba fi aye gba " Self Help" ati " Self Defence" ni eyi to n jẹ ki eeyan gbeja ara rẹ tabi eeyan rẹ bi Sunday Igboho se n se lọwọ yii.
Kabiesi ni aibikita fun ara ilu lo n yọ ijọba lẹnu kii ṣe Sunday Igboho ni iṣọro wọn.

Oríṣun àwòrán, @Oba
Koda, Oba ni lọjọ kan, akololo yoo pada pe baba lori eto aabo iran yoruba laipẹ.
O parọwa fun ijọba apapọ ati ipinlẹ lati tete wa nkan se soro eto aabo lasiko yii.
- Sunday Igboho yarí, ó fohùn ránsẹ́ sáwọn èèyàn tó ń pẹ̀gàn rẹ̀
- Olóṣèlú ẹ fi mí sílẹ̀, n kò fẹ́ owó tàbí ipò lọ́dọ̀ yín - Sunday Igboho yarí
- Igboho vs Fulani: Báyìí ni nǹkan ṣé ń lọ nílé Sunday Igboho lónìí
- Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho; Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán- Seriki Fulani
Oba Olugbon ti Orile Igbon ni a ṣi maa ri ọgọrun un akọni ti yoo dide bi Sunday Igboho laipẹ ti nkan ba n tẹsiwaju bayii
Kabiesi mẹnuba ipa to ko lati pari ede aiyede to waye laarin Sunday Ighoho ati Ooni ti Ile Ife seyin.
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Wo ǹkan mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sunday Igboho tí orúkọ rẹ̀ gbẹnu aráyé kán
- Sunday Igboho wà lọ́nà Ibarapa, Seriki Fulani ní àwọn kó níbiì lọ, àrọ̀wà ló kù fúnwà
- Wo ìgbésẹ̀ tí àwọn lọ́balọ́ba, ọlọ́pàá àti Seyi Makinde fẹ́ gbé lórí áàwọ Ibarapa
Koda, o gobriyin fun Sunday Ighoho pe ọmọ to gbọran ni to si bọwọ to yẹ fun ori ade.
Oba Francis Olusola Alao ni Ooni ti Ile Ife, Oba Adeye Ogunwusi olowo ori Olori Naomi Silekun ola naa si jẹ baba to ni ifẹ ọmọ pupọ.
- Àwọn olóṣèlú ti ń fowó bẹ̀ mí kí n má bá Fulani jà torí ìbò 2023, àmọ́ o ti bọ́ - Sunday Igboho
- Gomina Seyi Makinde ṣe ìpàdé lóru mọ́jú pẹ̀lú àwọn eèyàn Ibarapa ní Oke Ogun
- Lẹ́tà mi sí ààrẹ Buhari lóríi àwọn adári tó gba Fulani láàyè ní Nàìjíríà - Oluwo ti Iwo
- A ti ri pé wọ́n fẹ́ kí àwa Fulani kúrò ní ilẹ̀ Yoruba - Seriki Igangan





