Igboho vs Fulani vs Makinde: Gomina Makinde ṣe ìpàdé lóru mọ́jú pẹ̀lú àwọn eèyàn Ibarapa ní Oke Ogun

Oríṣun àwòrán, @Makinde
Gomina Makinde ṣe ipade loru mọju pẹlu awọn eeyan Ibarapa.
L'ọjọ Aiku ni gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ ṣe ipade pẹlu awọn alẹnulọrọ kan ni ẹkun Ibarapa ni Oke Ogun ni ipinlẹ Oyo.

Oríṣun àwòrán, @Makinde
Ipade naa ko yọ awọn alaga ijọba ibilẹ ati awọn aṣoju ijọba to n bẹ ni agbegbe Ibarapa silẹ.
Nibẹ ni Makinde ti fi idi ọrọ mulẹ wi pe iṣoro oun ni iṣoro to n koju awọn eeyan agbegbe naa.
- Bukola Saraki sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbésẹ̀ Sunday Igboho
- Igboho vs Fulani: Báyìí ni nǹkan ṣé ń lọ nílé Sunday Igboho lónìí
- Sunday Igboho yarí, ó fohùn ránsẹ́ sáwọn èèyàn tó ń pẹ̀gàn rẹ̀
- Mo ń padà bọ̀ ní Ibarapa lọ́sẹ́ tó ń bọ̀- Igboho; Gbogbo dúkìá mi làwọn ọmọ Igboho jó tán- Seriki Fulani
- Ìfẹ́ Yorùbá ló mú mi fi ẹ̀mí wéwu láti kojú ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
Ninu ọrọ ti o ba awọn eeyan agbegbe naa sọ niluu Igbo Ọra, Makinde ni oun mọ irora wọn.
Koda, bẹẹ sini abẹwo ti oun ṣe si agbegbe naa ni yoo mu ki ijọba ri ojutu si iṣoro eto aabo to n waye ni agbegbe naa.
Atẹjade ti wọn fi lede lati ọwọ akowe iroyin fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Taiwo Adisa lo fi idi alaye ti gomina Makinde ṣe mulẹ.
O ni abẹwo naa waye lasiko to n ṣe ipade pẹlu awọn aṣoju ijọba, ati awọn alaga ijọba ibilẹ lati Ibarapa Central, Ibarapa East atiIbarapa North, ni Igbo Ọra, l'oru ọjọ Aiku.
Igbese wo ni Makinde ti gbe bayii?
Makinde ni oun ti buwọ lu ifilọlẹ igbimọ alaafia ati eto aabo ni awọn ijọba ibilẹ.

Oríṣun àwòrán, @Makinde
Gomina sọ pe oun tun ti parọwa si gbogbo pẹlu alaye wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo tun ṣe agbekalẹ awọn eto aabo mii lati jẹ ki alafia jọba ni agbegbe naa.
Bakan naa lo ṣe alaye wi pe eto iforukọsilẹ fun idanimọ yoo waye fun gbogbo olugbe agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, @Makinde
Atẹjade naa tun fi idiẹ mulẹ wi pe Makinde kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn eeyan to padanu ẹmi wọn sinu iṣoro eto aabo ti ko fẹsẹ mulẹ ni agbegbe naa.
Makinde ni inu oun ko dun rara si nkan to ṣẹlẹ nibẹ.
Lara awọn eeyan to peju-pesẹ sibi ipade naa ni adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu 'Debọ Ogundoyin,
Awọn miran to tun wa nibẹ ni awọn kọmiṣọnna, alaga ijọba ibilẹ, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ati awọn aṣoju ijọba ni agbegbe Ibarapa.
- Ṣé lọ́ọ̀tọ̀ ní àkúdááyà wà? ẹ̀ wo ìrírí àwọn tó rí ènìyàn wọn tó kú láàyè
- Ẹ yé ṣí ìhòhò ara yín síta lórí ayélujára torí ‘Silhouette Challenge’ - Adeboye
- Òfin kónílé-ó-gbélé gbòde nílùú Igangan lórí ẹ̀rù pé Fulani le k'ógun wá lẹ́yìn àbẹ̀wò Igboho
- Wo bí o ṣe lè di ọmọ onílùú ní Dubai pẹ̀lú òfin tuntun orílẹ́èdè U.A.E.
- Wo ọ̀nà márùn ún tí o fi lè rí owó láti fi ṣòwò lọ̀dún 2021 pẹlu ìrọ̀rùn





















