Sunday Igboho: Agbejọ́rò Ozekhome ní Igboho ní láti gbàṣẹ ìdáàbòbò iléẹjọ́ káwọn ọlapáá má ba à lè mú u

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho

Lẹyin ti awọn ọlọpaa gbiyanju lati fi ọwọ ofin mu ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ọpọ eeyan ti n jade satilẹyin fun un.

Lara wọn ni gbajugbaja agbẹjọro, Mike Ozekhome (SAN) ti oun naa ti rọ Igboho lati gba aṣẹ idaabobo nile ẹjọ ki awọn ọlọpaa ma ba a le dunkooko lati fi ọwọ ofin mu un mọ.

Ozekhome sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Abamẹta ninu eyi to ti bu ẹnu atẹ lu igbiyanju awọn agbofinro to fẹ mu Igboho niluu Ibadan.

''Igboho ni ẹtọ labẹ ofin lati beere aṣẹ idaabobo nile ẹjọ ki awọn ọlọpaa tabi awọn ẹṣọ alaabo ma le dunkoko mọ ọ mọ,'' Ozekhime lo woye bẹẹ.

''Ileẹjọ yoo fun Igboho ni iru aṣẹ bẹẹ nitori ko si ẹri to daju pe o ṣe ohun to tapa si ofin.

Agbẹjọro agba naa ni awọn agbofinro le ranṣẹ pe Igboho ti wọn ba ni ẹri to daju pe o ti ṣẹ si ofin.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro

Ẹwẹ. ẹgbẹ ọmọ Oduduwa ni ipinlẹ Minnesota lorilẹede Amẹrika ti kilọ pe eera kan ko gbọdọ rin Igboho nitori o n sọrọ tako awọn daran daran to n huwa ọdaran nilẹ Yoruba.

Aarẹ ẹgbẹ ọhun, pasitọ Goke Odujole ṣalaye pe aṣiṣe nla ni yoo jẹ ti ijọba ba fi le mu Igboho.

O ni Igboho n ṣoju awọn Yoruba ni, kii ṣe pe o n da iṣẹ ara rẹ jẹ pẹlu nkna ti o n ṣe.

Sunday Igboho atawọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho

''Ọpọ ọmọ Yoruba ni inu wọn ko dun pẹlu bi eto abo ti mẹhẹ, ti iwa ijinigbe ati ifipa banilopọ sẹ di meji eepinni nilẹ Yoruba bayii,'' alufaa Odujole lo sọ bẹẹ.

O ni ti ijọba ba le mu Igboho, ọpọ ọdọ mii to le ju Igboho lọ yoo tun dide.

Àkọlé fídíò, Oladele Ogbeyemi Albert: Irin tí mò ń lò máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀mí kí ń tó gbẹ́ wọn sóh

Ọgbẹni Odujole ni eto abo ti mẹhẹ debi pe awọn eeyan lo n pese abo fun ara wọn kii ṣe ijọba mọ

O rọ ijọba lati fi ọwọ ofin mu awọn to pa Olufọn ilu Ifon ati Ọmọwe Fatai Aborode ni Ibarapa nipinlẹ Oyo.

Àkọlé fídíò, Badagry Historical Wells: Omi inú kànga Wawú ló ń kó ọpọlọ àwọn ẹrú lọ