Ọkùnrin ẹni ọdún 73 sá kúrò nílé lẹ́yìn tí ìyàwó rẹ̀ lóyín ìbẹta

Oríṣun àwòrán, @legitngnews
Obinrin ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn yii ko lero pe oju oun yoo ri iru nnkan bayii nigba to gba lati ṣe iyawo Pili Shaban ni nnkan bii ọdun mẹrindilogun sẹyin.
Igbesi aye Zawadi Mussa Ntaliligwa bẹrẹ si n dori kodo lẹyin ti ọkọ rẹ sa kuro nile ni kete to gbọ pe ọmọ mẹta lo wa ninu oyun inu rẹ.
Ṣaaju ni obiunrin naa ti kọkọ bi ọmọ marun un tẹlẹ ki oyun ibẹta ọhun to de.
- Oríṣìí àrùn mẹ́jọ tó máa ń ṣáábà mú aláboyún rèé
- Ọkùnrin kan gún olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́bẹ lórí N85,000 lẹ́yìn tó kọ̀ láti ṣèyàwó pẹ̀lú rẹ̀
- Fáàbàdà! Ìjọba ò sanwó fáwọn ajínigbé láti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé Kagara sílẹ̀- Lai Mohammed
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìlú Ondo fọkọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá
Gẹgẹ bii nnkan to sọ fun awọn akọroyin, ọkọ rẹ naa sa kuro nile laarin oṣu Karun un ọdun 2020, iyẹn lasiko ti ọwọja ajakalẹ arun Covid-19 kọkọ fi gbogbo agbaye logbologbo, ti ọpọ orilẹ-ede si wa ni igbele.
O ni "ibẹta ni mo bi loṣu kinni ọdun yii, awọn meji jẹ ọkunrin, ti eyii to kẹyin si jẹ obinrin."

Oríṣun àwòrán, @legitngnews
Obinrin naa to n gbe lagbegbe ila oorun Tanzania ni inu oṣi ati iṣẹ ni oun n gbe lati igba ti ọkọ oun to jẹ ẹni ọdun mẹtalelaadọrin ti fi oun silẹ pẹlu ọmọ mẹjọ lati maa tọju.
Ni bayii, o ni awọn alabagbe lo n da owo jọ nigba miran ti oun atawọn ọmọ naa fi n jẹun, koda, o ni oṣi naa pọ to bẹẹ ti oun padanu ọkan lara awọn ibẹta ọhun ninu oṣu Kẹji ọdun yii.
Nigba to n ṣalaye lori ohun pato to mu ọkọ kẹru ara rẹ jade kuro nile, o ni "mo gbagbọ o ko kuro nile nitori o ti mọ pe oyun naa maa na wa ni owo to pọ."
"A ko ni ija kankan lati nnkanbii ọdun mẹrindinlogun ti fẹ ara wa titi di igba ti mo ni oyun ọhun ko to kuro nile, to si ko gbogbo dukia wa, ati awọn aṣọ mi gan pẹlu."
- Ọ̀pọ̀ èèyàn lórí ayélujára dá Shina Peters lẹ́bi lórí ọ̀rọ̀ ọmọ tí Funmi Martins bí kó tó kú
- Wo ìgbà mẹ́rin táwọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé nílé ẹ̀kọ́ wọn ní Nàìjíríà
- Ìgbìmọ̀ ìwádìí ìfìyajẹni ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Eko fún ẹbí méjì ní ₦10m ẹnì kọ̀ọ̀kan
- Mo pàdánù owó tó lé ní N20m lọ́jà Shasha, mi ò padà síbẹ́ mọ́- Alhaji Nyako
- Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìlú Ondo fọkọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá
O ṣalaye pe lati igba ti ọkọ naa ti salọ, iṣẹ agbaṣẹ pẹlu iṣẹ ọmọ ọdọ ni oun n ṣe ki awọn naa to le jẹun lọpọ igba.
Zawadi pari ọrọ rẹ pe oun ko binu si ọkunrin naa bo tilẹ jẹ pe o fi oun silẹ lọ, bakan naa lo sọ pe oun ṣetan lati dariji to ba pinnu lati pada wa sile.
Lẹyin naa lo rọ awọn ọkunri lati maṣẹ kọ ojuṣẹ wọn ninu ile gẹgẹ baale lai ro bi nnkan ṣe le to lawujọ.
- Àwọn obìnrin mánigbàgbé tó ti kópa nínú sáà ìjọba tiwantiwa láti ọdún 1999
- Wo oríṣi oúnjẹ márùn ún tí kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn kan fẹ́ràn púpọ̀ ní Nàìjíríà
- Irọ́ ni pé wọ́n ti fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kagara sílẹ̀- Gomina ìpínlẹ̀ Niger
- Ìjọba ti ileẹ̀kọ́ pà lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú ṣèkọlù sí Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun
- Ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè (Customs) tẹ́lẹ̀ tó kú tí wọ́n fẹ̀sùn kíkó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù jẹ kan
















