Lekki toll gate protest, endsars: Ẹbí méjì gba ₦10m lẹ́yìn ìwádìí ìgbìmọ̀ ìwádìí ìfìyajẹni ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Eko

EndSARS

Oríṣun àwòrán, @followlasg

Igbimọ oluwadii ti ijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ lati ṣọfintoto ẹsun ifiyajẹni ti awọn eeyan ilu fi kan ọlọpaa ti bẹrẹ si n san owo gba mabinu fu awọn kan to gbe ẹjọ wa siwaju wọn.

Ninu ẹjọ to kan oloogbe Kudirat Adebayo Abayomi, ti wọn ni aṣita ibọn ọlọpa ran lọ si ọrun ọsan gangan loṣu Kẹrin ọdun 2017, igbimọ naa ni ki wọn fi awọn ọlọpaa ti aje ọrọ naa ṣi mọ lori jofin.

Igbimọ naa tun ni ki wọn fun ẹbi arabinrin na ni miliọnu mẹwaa naira owo gba mabinu.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro

Lẹyin naa ni wọn fun awọn ọmọ rẹ ni ẹbun ẹkọ ọfẹ, ti wọn si tun ni ki ileeṣẹ ọlọpaa kọ lẹta si mọlẹbi rẹ lati tọrọ aforiji lori iṣẹlẹ naa.

Olupẹjọ keji, Hannah Olugbode, to jẹ aṣerunniyọyọ wa siwaju igbimọ naa pẹlu ọpa lẹyin ti awọn oṣiṣẹ SARS fi aṣita ibọn fọ ẹsẹ rẹ lagbegbe Ijeshatedo, nipinlẹ Eko.

Igbimọ naa ni ki wọn fun oun naa ni miliọnu mẹwaa naira fun ohun to ti la kọja nitori iṣẹlẹ naa ati fun owo itọju.

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin oṣu diẹ ti wọn gbe igbimọ na kalẹ ki awọn to fara gba ninu aṣilo agbara awọn agbofinro le ri idajọ ododo gba.

EndSARS

Oríṣun àwòrán, @followlasg

Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi ẹjọ ni awọn eeyan gbe wa siwaju igbimọ naa, igbesẹ yii ni akọkọkọ to lamilaaka ti igbimọ naa gbe lati yanju ọrọ awọn olupẹjọ ọhun.

Bi ẹ ba ko gbagbe, ni nnkan bii oṣẹ meji sẹyin ni alaga igbimọ naa, adajọ Doris Okuwobi fun ileeṣẹ Lekki Concession Company, LCC, laṣẹ lati pada gba iṣakoso iloro Lekki Toll Gate, ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiiria faake kọri nitori awọn ẹmi to sọnu nibẹ logunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.

EndSARS

Oríṣun àwòrán, @followlasg

Iloro naa jẹ ọkan pataki lara awọn ibi ti iwọde lodi si aṣilo ipo SARS, iyẹn EndSARS ti waye ki iwọde ọhun to dojuru lọja naa lọhun.

Ẹwẹ, lọsẹ to kọja ni ọkan pataki lara awọn to n lewaju iwọde naa, Rinu Oduala sọ fun igbimọ naa pe oun ko ṣe ẹjọ mọ.

A ṣetán láti ṣèwádìí àwọn ọlọ́pàá tó fìyà jẹ àwọn tó ṣewọ́de ní Lekki tollgate- Hakeem Odumosu, Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá

Odumosu

Oríṣun àwòrán, @Odumosu

Kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti sọrọsoke lori iṣẹlẹ to waye lọjọ Abamẹta to kọja ni ipinlẹ Eko.

Nibẹ ni awọn ọdọ kan ti ṣewọde pe wọn ko gbọdọ tii ṣi Lekki Tollgate titi ti iwadii yoo fi pari lori ohun to ṣẹlẹ nibẹ lọdun to kọja.

Hakeem Odumosu to jẹ kọmiṣọnna awọn ọlọpaa ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu bi wọn ṣe huwa ko tọ si awọn ogoji ọdọ ti wọn sọ satimọle lori iwọde #Occupy Lekki tollgate.Lẹ́yìn ọgọ́rùn ún ọjọ́ tí wọn ti Lekki Toll Gate pa, ẹ wo owó gọbọi tíjọba Eko ń pàdánù

Lara awọn ti wọn sọ si atimọle na ni Debo Adebayo, gbajugbaja aderinpoṣonu ti wọn ni wọn gba aṣọ ọrun wọn, ti wọn tun na wọn ki wọn to rọ wọn sinu ọkọ lọ satimọle.Ta ló ń kẹ̀yìn àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà sírawọn lóríi àá ṣì Lekki toll gate, a ò ṣí i?

Ọpọlọpọ aworan lo ti jade lori ayelujara lori bi awọn agbofinro ṣe huwa ko tọ si awọn oluwọde naa ni eyi ti ko ba ofin Naijiria mu rara.

Eyi si ti fa ki awọn eeyan maa bu awọn ọlọpaa lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, BBC findings on lekki shooting: Ẹ wa wo àwọn tó ṣì ń wá ẹbí wọn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ End SARS 2020

Ọpọ ọmọ Naijiria n beere idi ti awọn agbofinro ṣe n ṣe a\won oluwọde bii ọdaran.

Kọmiṣọnna Odumosu ninu atẹjade to fi sita nipaṣe agbẹnusọ rẹ ni iwa naa ko dara to.

Olumuyiwa Adejobi to jẹ agbénusọ fun kọmiṣọnna Odumosu ni kete ti awọn fọnran fidio naa jade ni wọn ti kede pe ki iṣẹ iwadii bẹrẹ ki wọn si ṣafihan awọn ọlọpaa to huwa ko tọ naa.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

O ni iwa naa ko dun mọ kọmiṣọnna ninu rara.

Koda, o ti paṣẹ fun igbakeji Kọmiṣọnna, DCP Adegoke Fayoade to wa ni ẹkun agọ ọlọpaa Panti lati ṣiṣẹ lori fọnran fidio naa ko si fi oju awọn ọlọpaa ti ọrọ kan jofin.

Àkọlé fídíò, Bí àlááfíà yóò ṣe wà láàrin Fulani àti Yorùbá ni Ooni bá lọ sọ́dọ̀ Buhari- Ààfin Ile Ife