Shasa market Ibadan: Wo nkan tí a mọ̀ nípa wàhálà tó mú ẹ̀mí ẹnìkan lọ ní Shasa nílùú Ibadan

Ọja Shasa

Oríṣun àwòrán, Twitter/@Ifemosu Michael Adewale

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ ti ti ọjà Ṣaṣa nítorí rògbòdìyàn tó n wáyé níbẹ̀ láti ọjọ́ Ẹtì

Eeyan kan gbẹmi mi ninu ija to waye ni ọja Shasa nilu Ibadan lọjọ Ẹti.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ, sọ fun BBC Yoruba pe ẹni naa ku lasiko ti awọn janduku kọju ija si ara wọn.

Olopaa

Oríṣun àwòrán, Police

Ṣugbọn ṣa, iroyin to n lọ ni pe ija n waye laarin awọn eeyan to jẹ ẹya Yoruba ati Hausa ninu ọja naa.

BBC Yoruba gbọ wi pe ija naa bẹrẹ laarin ọkunrin sobata kan to jẹ Hausa, ati ọkunrin kan to jẹ ẹya Yoruba, eyi to pada yọri si iku ẹni to jẹ Hausa.

Bakan naa ni awọn fidio to n lọ lori ayelujara n sọ pe awọn eeyan ẹya Hausa ti n kọju ija si awọn to n gbe ni agbegbe Shasa lati ọjọ Ẹti ti ọrọ naa ti waye.

Ti wọn si n ba dukia, ile ati ọkọ wọn jẹ.

Amọ ninu ọrọ rẹ, Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe kii sẹ ija ẹlẹyamẹya.

O ni "ija naa kii sẹ ti ẹlẹyamẹya, laarin awọn ọmọ janduku to n wa ọna atijẹ ni.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

"Eeyan kan si kú nipaṣẹ bẹẹ."

O fikun pe awọn ọlọpaa ati eleto aabo miran ti wa ni agbegbe naa, ti alaafia si ti n jọba diẹdiẹ.

Àkọlé fídíò, Akure incest Momoh Usman case: Láti ẹni ọdún mẹ́tàlà ni Bàbá mi ti ń ba mi sùn- Fatimah Us

Lori iṣẹlẹ yii bakan naa, gomina ipinlẹ ọyọ, Seyi Makinde ti kede pe ki ọja Shasa p di titi pa.

Isede yoo si ma a waye laarin aago mẹfa irọlẹ si meje owurọ titi di asiko ti ijọba ba gbẹsẹ kuro lori ofin naa.

Àkọlé fídíò, 50 Year old Ajayi Folashade: Mo ti kọ́kọ́ dán an wò ní 80s àmọ́, ó kàn ṣáà ń wù mi náà ni