Yollywood: Mo Adebimpe gba omijé lójú Lateef Adedimeji, ayẹyẹ ọjọ́ ìbí da Saheed Balogun àti Fathia Wiliams pọ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram
Ọrọ ifẹ, bi adanwo ni. Eyi lo difa fun oṣere tiata Yoruba to bu sẹkun ayo. Kinni idi abajọ?
Gbogbo rẹ la o ṣalaye fun yin ni ẹkunrẹrẹ lai ṣẹ ọkan kan ku.
Saheed Balogun ati aya rẹ tẹlẹ, Fathia Willaims ṣe ọjọ ibi ni ọjọ kan naa laarin ọsẹ yii.
- Àwọn àgbà wo ló fọ́wọ́ ọlá gbá gbajúgbajà òṣèré Jamiu Afeez lójú tó ń wa ẹkún mu lóríi sinimá tó ṣe?
- Ìléeṣẹ́ tó ni Lekki Toll gate, LCC ti gbàkóso ǹkan rẹ̀ padà! Aṣẹ gùn ún
- Wo ìdí tí ìjọba Buhari fi ti àkáúǹtì àwọn tó ń ṣe kátà kárà owó ''cryptocurrency'' pa
- Àwọn jàndùkú ṣá ẹ̀ṣọ́ Amotekun àti ọlọ́pàá ní àdá àti àáké n'Ibadan
- Kábíyèsí Ooni ti forí jin Sunday Igboho lẹ́yìn tó túúbá- Ààfin Ile Ife
- Ìdí tí wọn kii fi jẹ́ kí obìnrin jẹ Ọ̀ọ̀ni ni Ile Ife
- FRSC: Èèyàn mẹ́jọ ló kù nínú ìjàmbá ọkọ̀ nípìnlẹ̀ Ògùn
- Ta ló pa ẹbí olùrànlọ́wọ́ Gómìnà Rotimi Akeredolu nínú oko rẹ̀ l'Ondo?
Wọnyii ni awọn iṣẹlẹ to ṣẹlẹ lagbo osẹre Yoruba lọsẹ yii.
Mo'bimpe gba omijé lójú Adedimeji
Gbajugbaja oṣere taita, Lateef Adedimeji ya agbado ha sawọn ololufẹ ere Yoruba lẹnu lẹyin to da omi loju poro poro.
Ki lo le mu Adedimeji bu omi loju gan an?
Ọrẹbinrin rẹ, Mo'bimpe Oyebade lo ya a lẹnu pẹlu ẹbun iyebiye ṣaaju ọjọ ibi rẹ.
Eyi lo mu ki lateef bu sẹkun ayọ

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mo'Bimpe Adebade
- Wo àwọn gbajúgbajà ojú ti EFCC máa ba ṣe ẹjọ́ ní 2021
- Ìdí tí wọn kii fi jẹ́ kí obìnrin jẹ Ọ̀ọ̀ni ni Ile Ife
- Ta ló pa ẹbí olùrànlọ́wọ́ Gómìnà Rotimi Akeredolu nínú oko rẹ̀ l'Ondo?
- Wo ìdí tí ìjọba Buhari fi ti àkáúǹtì àwọn tó ń ṣe kátà kárà owó ''cryptocurrency'' pa
- Ìtàn ayé Abiola Peller, ọlọ́wọ́ idán tó fi ọ̀bẹ gé ìyàwó rẹ̀ sí méjì
Fathia ati Saheed Balogun
Yoruba maa n sọ pe owo ti ọmọ ba ti wọ, okuta ti wọọ.
Otitọ ni pe Fathia ati Saheed Balogun ti kọ ara wọn silẹ gẹgẹ lọkọ laya bo tilẹ jẹ pe wọn bimọ fun ara wọn.
Amọ, ohun kan to maa n pa awọn mejeeji pọ lọdọọdun ni ayẹyẹ ọjọ ibi wọn.
Ọjọ karun un, oṣu keji, ọdun 2021 yii lawọn mejeeji tun ṣe ọjọ ibi wọn.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Fathia Balogun
Toyin Abraham
Ilumọọka oṣere tiata, Toyin Abraham ti di wolii obinrin.
Ninu fidio kan ti Toyin fi si oju opo Instagram rẹ lo ti ṣiwaju adura fawọn obinrin ti ko ti si nile ọkọ.
Toyin sọ ninu adura naa pe ibi kibi ti wọn ko ba ni pade ọkọ wọn, ki awọn ma lọ sibẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Toyin ni ki awọn obinrin ti ko ba ti lọ sile ọkọ ye ṣakọ si awọn ọkunrimọ.
Dele Odule
Agbaọjẹ oṣere Dele Odule ṣe ilanilọyẹ lori rọba idabobo fun ibalopọ ni tirẹ tori arun.
Ọgbẹni Odule sọ pe o maa n ti ọpọ eeyan loju lati beere fun rọba idaabobo nile itaja tabi ile ita oogun.
- Dúkìá mi tó tó N500m ni mo pàdánú, àmọ́ ó wù mí láti padà sí Igangan- Seriki Fulani
- Iléẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún méje ká lórí ẹ̀sùn àìjọgbé papọ̀
- Àgbálùmọ̀, ohun mẹ́fà tó ń ṣe lára tí o kò mọ̀
- Hisbah Kano mú ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó n ṣe káràkátà ọtí bíà níta
- Àwọn jàndùkú ṣá ẹ̀ṣọ́ Amotekun àti ọlọ́pàá ní àdá àti àáké n'Ibadan
O fi ara rẹ ṣe apejuwe ẹni ti o fẹ ra rọba idaabo bo ṣugbọn ti ko le darukọ ohun to fẹ ra gan an.
Lowe lowe lo Odule fi n beere fun rọba idaabo bo lọwọ ọmọ to n taja.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Ṣugbọn ọrọ Odule ko gba ibi kan ye ọmọbinrin olutaja ọhun nitori ko sọ oju abẹ nikoo.
















