Amotekun attack: Àwọn jàndùkú ṣá ẹ̀ṣọ́ Amotekun àti ọlọ́pàá ní àdá àti àáké n'Ibadan

Ẹṣọ Amotekun

Oríṣun àwòrán, Twitter/Oyo State Government

Awọn janduku kọlu awọn ẹṣọ alaabo Amotekun ni ijọba ibilẹ Ona Ara ni ipinlẹ Oyo.

Ẹgbẹ awọn onile ni agbegbe Odeyale lo pe awọn agbofinro fun iranwọ lẹyin ikọlu awọn janduku lagbegbe naa.

Alakoso ẹṣọ Amotekun ni ijọba Ona Ara, Ọgbẹni Adelakun ṣalaye pe awọn janduku fi aake ati ada ṣa ẹṣọ Amotekun mẹrin ti wọn si farapa yanayana.

Ọgbẹni Adelakun sọ pe mẹrin ninu awọn ẹṣọ Amotekun ni wọn wa nile iwosan UCH nibi ti wọn ti n gba itọju.

O ni iṣẹ iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ to ṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji